1
Allāhu fi ìyálẹ̀ta búra.
2
Ó tún fi alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú búra.
3
Olúwa rẹ kò pa ọ́ tì, kò sì bínú sí ọ.
4
Dájúdájú ọ̀run lóore fún ọ ju ayé.
5
Dájúdájú láìpẹ́ Olúwa rẹ máa fún ọ ní (oore púpọ̀ ní ọ̀run). Nítorí náà, o sì máa yọ́nú sí i.
6
Ṣé (Allāhu) kò rí ọ ní ọmọ-òrukàn ni? Ó sì fún ọ ní ibùgbé.
7
Ó sì rí ọ ní aláìmọ̀nà (ìyẹn ṣíwájú ìsọ̀kalẹ̀ ìmísí). Ó sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́.1
8
Ó tún rí ọ ní aláìní, Ó sì rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀.
9
Nítorí náà, ní ti ọmọ-òrukàn, má ṣe jẹ gàba (lé e lórí).
10
Ní ti alágbe, má sì ṣe jágbe (mọ́ ọn).
11
Ní ti ìdẹ̀ra Olúwa rẹ, sọ ọ́ jáde.