1
Ṣé A kò ṣípayá igbá-àyà rẹ fún ọ bí?
2
A sì gbé ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò lọ́rùn rẹ,
3
èyí tí ó wọ̀ ọ́ lọ́rùn.1
4
A sì gbé ìrántí orúkọ rẹ ga fún ọ.
5
Nítorí náà, dájúdájú ìdẹ̀kùn wà lẹ́yìn ìnira.
6
Dájúdájú ìdẹ̀kùn wà lẹ́yìn ìnira sẹ́.
7
Nítorí náà, nígbà tí o bá bùṣe (lórí ohun tí ó jẹmọ́ táyé), gbìyànjú (dáadáa lórí ìjọ́sìn).
8
Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì ni kí o ṣojú kòkòrò oore sí.