1
Sọ pé: “Mo sá di Olúwa àwọn ènìyàn,
2
Ọba àwọn ènìyàn,
3
Ọlọ́hun àwọn ènìyàn,1
4
níbi aburú (Èṣù) oníròyíròyí, olùsásẹ́yìn (fún ẹni tó bá ń dárúkọ Allāhu.
5
(Èṣù ni) ẹni tí ó ń kó ròyíròyí sínú àwọn ọkàn ènìyàn.
6
(Èṣù náà) wà nínú àwọn àlùjànnú àti àwọn ènìyàn.”