1
Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.1
2
Gbogbo ẹyìnń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa2 gbogbo ẹ̀dá,
3
Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run,
4
Olùkápá-ọjọ́-ẹ̀san.
5
Ìwọ nìkan ni à ń jọ́sìn fún. Ọ̀dọ̀ Rẹ nìkan sì ni à ń wá oore sí.1
6
Fi ẹsẹ̀ wa rinlẹ̀ l’ójú ọ̀nà tààrà (’Islām),1
7
ọ̀nà àwọn tí O ṣe ìdẹ̀ra fún,yàtọ̀ sí (ọ̀nà) àwọn ẹni-ìbínú (ìyẹn, àwọn yẹhudi) àti (ọ̀nà) àwọn olùṣìnà (ìyẹn, àwọn nasọ̄rọ̄).