Sọ pé: “Mo sá di Olúwa òwúrọ̀ kùtùkùtù
níbi aburú ohun tí Ó dá,1
àti níbi aburú òru nígbà tí ó bá ṣóòkùn,
àti níbi aburú àwọn (òpìdán) tó ń fẹnu fátẹ́gùn túẹ́túẹ́ sínú àwọn ońdè,
àti níbi aburú onílara nígbà tí ó bá ṣe ìlara.”