Sọ pé: “Òun ni Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo.
Allāhu ni Aṣíwájú tí ẹ̀dá ní bùkátà sí níbi jíjọ́sìn fún Un àti títọrọ oore ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀, tí Òun kò sì ní bùkátà sí wọn ní ọ̀nà kan kan.
Kò bímọ. Wọn kò sì bí I.
Kò sì sí ẹnì kan kan tí ó jọ Ọ́.”1