Gbogbo Islam Library
1

Allāhu fi òòrùn àti ìyálẹ̀ta rẹ̀ búra.

2

Ó tún fi òṣùpá nígbà tí ó bá (yọ) tẹ̀lé (òòrùn) búra.

3

Ó tún fi ọ̀sán nígbà tí ó bá mú ìmọ́lẹ̀ bá òkùnkùn òru búra.

4

Ó tún fi alẹ́ nígbà tí ó bá bo ọ̀sán mọ́lẹ̀ búra.

5

Ó tún fi sánmọ̀ àti Ẹni tí Ó mọ ọ́nbúra?

6

Ó tún fi ilẹ̀ àti Ẹni tí Ó tẹ́ ẹ kalẹ̀ pẹrẹsẹ búra.

7

Ó tún fi ẹ̀mí (ènìyàn) àti Ẹni tí Ó ṣe (oríkèé rẹ̀) dọ́gba búra.

8

Ó sì fi ẹ̀ṣẹ̀ (tí ẹ̀mí lè dá) àti ìbẹ̀rù rẹ̀ mọ̀ ọ́n.

9

Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àfọ̀mọ́ (ẹ̀mí ara) rẹ̀ (níbi ẹ̀ṣẹ̀), ó mà ti jèrè.1

10

Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi (ìwà ẹ̀ṣẹ̀) ba ẹ̀mí (ara) rẹ̀ jẹ́, ó mà ti pàdánù.

11

Ìjọ Thamūd pe òdodo ní irọ́ nípa ìtayọ ẹnu-ààlà wọn.

12

(Rántí) nígbà tí ẹni tí orí rẹ̀ burú jùlọ nínú wọn sáré dìde (láti gún ràkúnmí pa).

13

Nígbà náà, Òjíṣẹ́ Allāhu sọ fún wọn pé: “(Ẹ fi) abo ràkúnmí Allāhu àti omi rẹ̀ (sílẹ̀).”

14

Wọ́n pè é ní òpùrọ́. Wọ́n sì gún (ràkúnmí) pa. Nítorí náà, Olúwa wọn pa wọ́n rẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ó sì fi ìparun náà kárí wọn.

15

(Ẹni tó gún ràkúnmí pa) kò sì páyà ìkángun ọ̀rọ̀ wọn.