Gbogbo Islam Library
1

Èmi (Allāhu) ń fi ìlú yìíbúra.

2

Ìwọ sì ní ẹ̀tọ́ sí ìlú yìí (láti jagun nínú rẹ̀).1

3

Èmi (Allāhu) ń fi òbí àti ohun tó bí búra.

4

Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn sínú ìṣòro.

5

Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò ní agbára lórí òun ni?

6

Ó (sì) ń wí pé: “Èmi ti bàná dúkìá ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (láti fi tako Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -)”

7

Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò rí òun ni?

8

Ṣé A kò ṣe ojú méjì fún un?

9

Àti ahọ́n pẹ̀lú ètè méjì (tí A ṣe fún un)?

10

A sì fi ọ̀nà méjì mọ̀ ọ́n.

11

Kò sì lọ rin ojú-ọ̀nà orí àpáta tó ṣòroó gùn fún ìgbàlà ẹ̀mí níbi Iná!

12

Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ ojú-ọ̀nà orí àpáta tó ṣòroó gùn fún ìgbàlà ẹ̀mí?

13

(Òhun ni) títú ẹrú sílẹ̀ lóko ẹrú.

14

Tàbí fífún ènìyàn ní oúnjẹ ní ọjọ́ ebi.

15

(Ẹ lè fún) ọmọ-òrukàn nínú ẹbí,

16

tàbí mẹ̀kúnnù tí kò ní gá tí kò ní go (olòṣì paraku).

17

Lẹ́yìn náà, kí ó wà nínú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ń gbara wọn níyànjú sùúrù ṣíṣe, tí wọ́n sì tún ń gbara wọn níyànjú àánú ṣíṣe.

18

Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò ọwọ́ ọ̀tún.

19

Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, àwọn ni èrò ọwọ́ òsì.1

20

Wọ́n máa ti àwọn ìlẹ̀kùn Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá.