Gbogbo Islam Library

88 - The Overwhelming - Al-Ghāshiyah

:1

Ṣebí ọ̀rọ̀ nípa ohun tó máa bo ẹ̀dá mọ́lẹ̀ ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?

:2

Àwọn ojú kan yóò wálẹ̀ (ní ti ìyẹpẹrẹ) ní ọjọ́ yẹn.

:3

Wọ́n ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó (ni nílé ayé).

:4

Wọ́n sì máa wọ inú Iná tó gbóná janjan (ní ọ̀run).

:5

Wọ́n sì máa fún (wọn) ní omi ìṣẹ́lẹ̀rú gbígbóná mu.

:6

Kò sí oúnjẹ kan fún wọn àyàfi igi ẹlẹ́gùn-ún gbígbẹ.

:7

Kò níí mú wọn sanra. Kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ebi.

:8

Àwọn ojú kan yó sì kún fún ìgbádùn ní ọjọ́ yẹn

:9

nítorí pé (ó) yọ́nú sí (ẹ̀san) iṣẹ́ rẹ̀.

:10

(Ó máa) wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra gíga.

:11

Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ nínú rẹ̀.

:12

Omi ìṣẹ́lẹ̀rú tó ń ṣàn wà nínú rẹ̀.

:13

Àwọn ibùsùn tí wọ́n gbé sókè wà nínú rẹ̀,

:14

àti àwọn ife ìmumi tí wọ́n gbé kalẹ̀ (sí àrọ́wọ́tó wọn),

:15

àti àwọn ìrọ̀rí tí wọ́n tò sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn,

:16

àti àwọn ìtẹ́ àtẹ́ẹ̀ká.

:17

Nítorí náà, ṣé wọn kò wòye sí ràkúnmí, bí A ti ṣẹ̀dá rẹ̀ ni;

:18

àti sánmọ̀, bí A ti ṣe gbé e sókè;

:19

àti àpáta, bí A ti ṣe gbé e nàró (sínú ilẹ̀);

:20

àti ilẹ̀, bí A ti ṣe tẹ́ ẹ sílẹ̀ pẹrẹsẹ?

:21

Nítorí náà, ṣèrántí. Ìwọ kúkú ni olùṣèràntí.

:22

Ìwọ kì í ṣe ajẹni-nípá lórí wọn

:23

àfi ẹni tí ó bá pẹ̀yìndà (sí òdodo), tí ó sì ṣàì gbàgbọ́.

:24

Allāhu sì máa jẹ ẹ́ níyà tó tóbi jùlọ.

:25

Dájúdájú ọ̀dọ̀ Wa ni àbọ̀ wọn wà.

:26

Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l’A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ wọn.