All Islam Directory
1

Ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni gíga jùlọ.

2

Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá. Ó sì ṣe (oríkèé-ríkèé rẹ̀) ní dọ́gbadọ́gba.

3

Ẹni tí Ó yan kádàrá (fún ẹ̀dá). Ó sì tọ́ ọ sọ́nà.1

4

Ẹni tí Ó mú koríko tútù hù jáde,

5

Ó sì sọ ọ́ di gbígbẹ tó dúdú.

6

Àwa yóò máa ké (al-Ƙur’ān) fún ọ. Ìwọ kò sì níí gbàgbé.

7

Àyàfi ohun tí Allāhu bá fẹ́.Dájúdájú Ó mọ gban̄gba àti ohun tó pamọ́.

8

Àwa yó sì ṣe iṣẹ́ rere ní ìrọ̀rùn fún ọ.

9

Nítorí náà, ṣèrántí ní àyè tí ìrántí ti wúlò.1

10

Ẹni tí ó máa páyà (Allāhu) máa lo ìrántí.

11

Olórí-burúkú sì máa takété sí i.

12

(Òun sì ni) ẹni tí ó máa wọ inú Iná tó tóbi.

13

Lẹ́yìn náà, kò níí kú sínú rẹ̀, kò sì níí ṣẹ̀mí (àlàáfíà).

14

Dájúdájú ẹni tí ó bá ṣe àfọ̀mọ́ (ẹ̀sìn rẹ̀) ti jèrè.1

15

Ó sì rántí orúkọ Olúwa rẹ̀, ó sì kírun.

16

Rárá, ńṣe l’ẹ̀ ń gbé àjùlọ fún ìṣẹ̀mí ayé.

17

Ọ̀run sì lóore jùlọ, ó sì máa wà títí láéláé.

18

Dájúdájú èyí wà nínú àwọn tákàǹdá àkọ́kọ́,

19

tákàdá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti (Ànábì) Mūsā.