Gbogbo Islam Library

85 - The Mansions of the Stars - Al-Burūj

:1

(Allāhu) fi sánmọ̀ tí àwọn ibùsọ̀ (òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀) wà nínú rẹ̀ búra.

:2

Ó tún fi ọjọ́ tí wọ́n ṣe ní àdéhùn (ìyẹn Ọjọ́ Àjíǹde) búra.

:3

Ó tún fi olùjẹ́rìí àti ohun tó jẹ́rìí sí búra.

:4

A ṣẹ́bi lé àwọn tó gbẹ́ kòtò (iná),

:5

(ìyẹn) iná tí wọ́n ń fi igi kò (nínú kòtò).

:6

(Rántí) nígbà tí wọ́n jókòó sí ìtòsí rẹ̀.

:7

Wọ́n sì ń wo ohun tí wọ́n ń ṣe fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

:8

Wọn kò rí àlèébù kan (wọn kò sì kórira kiní kan) lára wọn bí kò ṣe pé, wọ́n ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu, Alágbára, Ẹlẹ́yìn,

:9

Ẹni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ni Ẹlẹ́rìí lórí gbogbo n̄ǹkan.

:10

Dájúdájú àwọn tó fi ìnira kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, lẹ́yìn náà tí wọn kò ronú pìwàdà, ìyà iná Jahanamọ ń bẹ fún wọn. Ìyà iná tó ń jó sì wà fún wọn.

:11

Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tiwọn ni àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá.

:12

Dájúdájú ìgbámú ti Olúwa rẹ mà le.

:13

Dájúdájú Òun ni Ó pìlẹ̀ (ẹ̀dá), Ó sì máa dá (ẹ̀dá) padà (fún àjíǹde).

:14

Òun ni Aláforíjìn, Olólùfẹ́ (ẹ̀dá),

:15

Òun l’Ó ni Ìtẹ́-ọlá, Ológo (Ẹni-ọ̀wọ̀ jùlọ),

:16

Olùṣe-ohun-t’Ó-bá-fẹ́.

:17

Ṣebí ìró àwọn ọmọ ogun ti dé ọ̀dọ̀ rẹ,

:18

(ọmọ ogun) Fir‘aon àti (ìjọ) Thamūd?

:19

Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ sì ń pe òdodo ní irọ́.

:20

Allāhu sì yí wọn ká lẹ́yìn wọn.

:21

Àmọ́ sá, ohun (tí A fi ránṣẹ́ sí ọ ni) al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé,

:22

tí ó wà nínú wàláà tí wọ́n ń ṣọ́.