Gbogbo Islam Library

84 - The Sundering - Al-'Inshiqāq

:1

Nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ

:2

  • ó gbọ́, ó sì tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ̀ ni. Ó sì di dandan fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀-

:3

àti nígbà tí A bá fẹ ilẹ̀ lójú,

:4

ó máa ju ohun tí ó wà nínú rẹ̀ síta, ó sì máa pa sófo

:5

  • ó gbọ́, ó sì tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ̀ ni. Ó sì di dandan fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ - (ní ọjọ́ yẹn ni ẹ̀dá máa rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀)

:6

Ìwọ ènìyàn dájúdájú ìwọ ń ṣe iṣẹ́ kárakára ní iṣẹ́ àṣepàdé Olúwa rẹ. O sì máa mú un pàdé Rẹ̀.

:7

Nítorí náà, ní ti ẹni tí wọ́n bá fún ní ìwé iṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀,

:8

láìpẹ́ A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ (rẹ̀) ní ìṣírò ìrọ̀rùn.

:9

Ó sì máa padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra) lẹ́ni ìdùnnú.

:10

Ní ti ẹni tí wọ́n bá sì fún ní ìwé iṣẹ́ rẹ̀ láti ẹ̀yìn rẹ̀,1

:11

láìpẹ́ ó máa kígbe ìparun.

:12

Ó sì máa wọ inú Iná tó ń jó.

:13

Dájúdájú ó ti wà láààrin àwọn ènìyàn rẹ̀ lẹ́ni ìdùnnú (sí àìgbàgbọ́ nílé ayé).

:14

Dájúdájú ó lérò pé òun kò níí padà (sí ọ̀dọ̀ Allāhu ni).

:15

Bẹ́ẹ̀ ni, (ó máa padà). Dájúdájú Olúwa rẹ̀ jẹ́ Olùríran nípa rẹ̀.

:16

Nítorí náà, Èmi (Allāhu) ń fi àwòǹpapa búra.

:17

Mo tún ń fi òru àti ohun tí ó kó jọ sínú rẹ̀ búra.

:18

Mo tún ń fi òṣùpá nígbà tí ó bá dégbá (tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kún) búra.

:19

Dájúdájú ẹ̀yin yóò máa bọ́ sínú wàhálà kan láti inú wàhálà kan.

:20

Kí l’ó ṣe wọ́n ná tí wọn kò fi gbàgbọ́ ní òdodo?

:21

Nígbà tí wọ́n bá sì ké al-Ƙur’ān fún wọn, wọn kò níí forí kanlẹ̀.

:22

Rárá, ńṣe ni àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ń pè é ní irọ́.

:23

Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ (sínú ọkàn wọn).

:24

Nítorí náà, fún wọn ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro.

:25

Àyàfi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ẹ̀san tí kò níí pinń bẹ fún wọn.