Gbogbo Islam Library

81 - The Overthrowing - At-Takwīr

:1

Nígbà tí wọ́n bá ká òòrùn kóróbójó dànù,

:2

àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri,

:3

àti nígbà tí wọ́n bá mú àwọn àpáta rìn (kúrò ní àyè wọn, tí wọ́n kù wọ́n dànù),

:4

àti nígbà tí wọ́n bá pa àwọn ràkúnmí aboyún tì,

:5

àti nígbà tí wọ́n bá ko àwọn ẹranko jọ,

:6

àti nígbà tí wọ́n bá mú àwọn agbami odò gbiná,

:7

àti nígbà tí wọ́n bá so àwọn ẹ̀mí pọ̀ mọ́ra wọn, (ẹni rere pẹ̀lú ẹni rere, ẹni ibi pẹ̀lú ẹni ibi)

:8

àti nígbà tí ọmọbìnrin tí wọ́n bò mọ́lẹ̀ láàyè bá bèèrè pé

:9

ẹ̀ṣẹ̀ wo ni wọ́n pa òun fún,

:10

àti nígbà tí wọ́n bá ṣí àwọn tákàdá (iṣẹ́ ẹ̀dá) sílẹ̀,

:11

àti nígbà tí wọ́n bá ká sánmọ̀ kúrò lókè,

:12

àti nígbà tí wọ́n bá mú iná Jẹhīm jò fòfò,

:13

àti nígbà tí wọ́n bá sún Ọgbà Ìdẹ̀ra mọ́ (àwọn onígbàgbọ́ òdodo),

:14

(nígbà náà ni) ẹ̀mí (kọ̀ọ̀kan) yóò mọ ohun tí ó mú wá (nínú iṣẹ́ ire àti iṣẹ́ ibi).

:15

Nítorí náà, Èmi (Allāhu) ń fi àwọn ìràwọ̀ tó ń yọ ní alẹ́, tó ń wọ̀ọ̀kùn ní ọ̀sán búra,

:16

(ìyẹn) àwọn ìràwọ̀ tó ń rìn lọ rìn bọ̀, tó ń wọ̀ọ̀kùn sí ibùwọ̀ wọn.

:17

Mo tún fi alẹ́ nígbà tí ó bá lọ búra.1

:18

Mo tún fi òwúrọ̀ nígbà tí ó bá mọ́lẹ̀ búra.

:19

Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán Jibrīl) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé,1

:20

alágbára, ẹni pàtàkì ní ọ̀dọ̀ Ẹni t’Ó ni Ìtẹ́-ọlá,

:21

ẹni tí wọ́n ń tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ níbẹ̀ yẹn (nínú sánmọ̀), olùfọkàntán.

:22

Àti pé ẹni yín (Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) kì í ṣe wèrè.

:23

Ó kúkú rí i nínú òfurufú kedere.1

:24

Àti pé kì í ṣe ahun (tàbí ẹni-afurasí) lórí ìró ìkọ̀kọ̀ (tí A fi ránṣẹ́ sí i).

:25

Al-Ƙur’ān kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) Èṣù, ẹni ẹ̀kọ̀.

:26

Nítorí náà, ibo l’ẹ̀ ń lọ?

:27

Kí sì ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.

:28

(Ó wà) fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti dúró déédé.

:29

Ẹ̀yin kò sì níí fẹ́ (láti dúró déédé) àyàfi tí Allāhu bá fẹ́, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.