Gbogbo Islam Library

82 - The Cleaving - Al-'Infiţār

:1

Nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,1

:2

àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri,

:3

àti nígbà tí àwọn ibúdò bá ṣàn jára wọn,

:4

àti (nígbà tí A bá ta ilẹ̀ sókè), tí A sì mú àwọn òkú jáde (láàyè) láti inú àwọn sàréè,

:5

(nígbà náà ni) ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò mọ ohun tí ó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun tí ó fi sẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀).

:6

Ìwọ ènìyàn, kí ni ó tàn ọ́ jẹ nípa Olúwa rẹ, Alápọ̀n-ọ́nlé,

:7

Ẹni t’Ó ṣẹ̀dá rẹ? Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ ní pípé. Ó sì mú ọ dọ́gba jalẹ̀ léèyàn.

:8

Ó to ẹ̀yà ara rẹ papọ̀ sínú èyíkéyìí àwòrán tí Ó fẹ́.

:9

Rárá! Bí kò ṣe pé ẹ̀ ń pe Ọjọ́ ẹ̀san ní irọ́.

:10

Dájúdájú àwọn ẹ̀ṣọ́ sì wà ní ọ̀dọ̀ yín.

:11

(Wọ́n jẹ́) alápọ̀n-ọ́nlé, òǹkọ̀wé-iṣẹ́ ẹ̀dá.

:12

Wọ́n mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

:13

Dájúdájú àwọn ẹni rere yóò kúkú wà nínú ìgbádùn.

:14

Dájúdájú àwọn ẹni ibi yó sì kúkú wà nínú iná Jẹhīm.

:15

Wọn yóò wọ inú rẹ̀ ní Ọjọ́ ẹ̀san.

:16

Wọn kò sì níí kúrò nínú rẹ̀.

:17

Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san?

:18

Lẹ́yìn náà, kí ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san?

:19

(Ọjọ́ ẹ̀san ni) ọjọ́ tí ẹ̀mí kan kò níí kápá kiní kan fún ẹ̀mí kan. Gbogbo àṣẹ ọjọ́ yẹn sì ń jẹ́ ti Allāhu.