1
Ègbé ni fún gbogbo abúnilójú-ẹni, abúnilẹ́yìn-ẹni,
2
ẹni tí ó kó dúkìá jọ, tí ó sì kà á lákàtúnkà (láì ná an fún ẹ̀sìn).
3
Ó ń lérò pé dájúdájú dúkìá rẹ̀ yóò mú un ṣe gbére (nílé ayé).
4
Rárá (kò rí bẹ́ẹ̀). Dájúdájú wọ́n máa kù ú lókò sínú Hutọmọh ni.
5
Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Hutọmọh?
6
(Òhun ni) Iná Allāhu tí wọ́n ń kò (tó ń jó geregere),
7
èyí tí ó máa jó (ẹ̀dá) wọ inú ọkàn lọ.
8
Dájúdájú wọ́n máa ti (àwọn ìlẹ̀kùn) Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá.
9
(Wọ́n máa wà) láààrin àwọn òpó kìrìbìtì gíga (nínú Iná).