Ṣé o kò wòye sí bí Olúwa rẹ ti ṣe ọ̀rọ̀ ìjọ elérin ni?
Ṣé kò sọ ète wọn di òfo àti anù bí?
Ó sì rán àwọn ẹyẹ níkọ̀níkọ̀ sí wọn.
Wọ́n ń jù wọ́n ní òkúta amọ̀ (tó ti gbaná sára).
Ó sì sọ wọ́n di bíi pòpórò gbígbẹ tí ẹranko jẹ lájẹdàsílẹ̀.