Gbogbo Islam Library

103 - The Declining Day - Al-`Aşr

:1

Allāhu fi àkókò ìrọ̀lẹ́ ayé búra.

:2

Dájúdájú ènìyàn wà nínú òfò.

:3

Àyàfi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ òdodo láààrin ara wọn, tí wọ́n sì tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ sùúrù láààrin ara wọn.