1
Wíwá oore ayé ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ fún ìyanràn ṣíṣe ti kó àìrójú fẹ́sìn ba yín
2
títí ẹ fi wọ inú sàréè.
3
Rárá (kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀, àmọ́) láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.
4
Lẹ́yìn náà, ní ti òdodo, láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.
5
Ní ti òdodo, tí ó bá jẹ́ pé ẹ ni ìmọ̀ àmọ̀dájú ni (ẹ̀yin ìbá tí ṣe bẹ́ẹ̀).
6
Dájúdájú ẹ máa rí iná Jẹhīm.
7
Lẹ́yìn náà, dájúdájú ẹ máa fi ojú rí i ní àrídájú.
8
Lẹ́yìn náà, dájúdájú ní ọjọ́ yẹn wọ́n máa bi yín léèrè nípa ìgbádùn (ayé yìí).