Gbogbo Islam Library
1

Àkókò ìjáyà.

2

Kí ni Àkókò ìjáyà?

3

Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Àkókò ìjáyà?

4

(Òhun ni) ọjọ́ tí ènìyàn yó dà bí àfòpiná tí wọ́n fọ́nká síta,

5

àwọn àpáta yó sì dà bí ẹ̀gbọ̀n òwú tí wọ́n gbọ̀n dànù.

6

Nítorí náà, ní ti ẹni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá tẹ̀wọ̀n,

7

ó sì máa wà nínú ìṣẹ̀mí tó máa yọ́nú sí.

8

Ní ti ẹni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá sì fúyẹ́,

9

Hāwiyah sì ni ibùgbé rẹ̀.

10

Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀?

11

(Òhun ni) Iná gbígbóná tó ń jó gan-an.