1
Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní ìmìtìtì rẹ̀,
2
àti (nígbà) tí ilẹ̀ bá tú àwọn ẹrù tó wúwo nínú rẹ̀ jáde,
3
ènìyàn yó sì wí pé: “Kí l’ó mú un?”
4
Ní ọjọ́ yẹn ni (ilẹ̀) yóò sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìró rẹ̀ (tí ẹ̀dá gbé orí ilẹ̀ ṣe).
5
Nítorí pé dájúdájú Olúwa rẹ l’Ó fún un ní àṣẹ (láti sọ̀rọ̀).
6
Ní ọjọ́ yẹn, àwọn ènìyàn yóò máa gba ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ nítorí kí wọ́n lè fi àwọn iṣẹ́ wọn hàn wọ́n.
7
Nítorí náà, ẹni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere ní òdíwọ̀n ọmọ iná-igún, ó máa rí i.
8
Ẹni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ aburú ní òdíwọ̀n ọmọ iná-igún, ó máa rí i.1