Gbogbo Islam Library
1

Dájúdájú Àwa sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ nínú Òru Abiyì.1

2

Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Òru Abiyì?

3

Òru Abiyì lóore ju ẹgbẹ̀rún oṣù.

4

Àwọn mọlāika àti Jibrīl yó sì máa sọ̀kalẹ̀ nínú òru náà pẹ̀lú àṣẹ Olúwa wọn fún gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan.

5

Àlàáfíà ni òru náà títí di àsìkò àfẹ̀mọ́júmọ́.