Gbogbo Islam Library
1

Ké (al-Ƙur’ān) pẹ̀lú orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá.

2

Ó ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara ẹ̀jẹ̀ dídì.

3

Ké e. Olúwa rẹ ni Alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ.

4

Ẹni tí Ó fi ìmọ̀ nípa gègé ìkọ̀wé mọ ènìyàn.

5

Ó fi ìmọ̀ tí ènìyàn kò mọ̀ mọ̀ ọ́n.

6

Ní ti òdodo, dájúdájú ènìyàn kúkú ń tayọ ẹnu-ààlà

7

nítorí pé ó rí ara rẹ̀ ní ọlọ́rọ̀.

8

Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni àbọ̀ ẹ̀dá.

9

Sọ fún mi nípa ẹni tó ń kọ̀

10

fún ẹrúsìn kan nígbà tí (ẹrúsìn náà) kírun!

11

Sọ fún mi (nípa ẹ̀san rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó wà lórí ìmọ̀nà (’Islām)

12

tàbí pé ó pàṣẹ ìbẹ̀rù (Allāhu)!

13

Sọ fún mi (nípa ìyà rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó pe òdodo ní irọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i?

14

Ṣé kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń rí (òun ni?)

15

Rárá (ọ̀rọ̀ kò rí bí ọ̀tá Allāhu ṣe rò ó sí. Dájúdájú tí kò bá jáwọ́ (níbi dídí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lọ́wọ́), dájúdájú A máa fi àásó orí2 rẹ̀ wọ́ ọ (sínú Iná);

16

àásó orí òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.

17

Nítorí náà, kí ó pe àwọn olùbájókòó rẹ̀.

18

Àwa máa pe àwọn mọlāika ẹ̀ṣọ́ Iná.

19

Rárá (ọ̀rọ̀ kò rí bí ó ṣe ń sọ nípa Wa). Má ṣe tẹ̀lé tirẹ̀. Forí kanlẹ̀ (kí o kírun), kí o sì súnmọ́ (Allāhu).