Gbogbo Islam Library

77 - The Emissaries - Al-Mursalāt

:1

Allāhu fi àwọn atẹ́gùn tó ń sáré ní tẹ̀léǹtẹ̀lé búra.

:2

Ó fi àwọn ìjì atẹ́gùn tó ń jà búra.

:3

Ó fi àwọn atẹ́gùn tó ń tú èṣújò ká búra.

:4

Ó fi àwọn tó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́ búra.

:5

Ó fi àwọn mọlāika tó ń mú ìrántí wá (bá àwọn Òjíṣẹ́) búra.

:6

(Ìrántí náà jẹ́) àwíjàre tàbí ìkìlọ̀.

:7

Dájúdájú ohun tí A ṣe ní àdéhùn fún yín kúkú máa ṣẹlẹ̀.

:8

Nítorí náà, nígbà tí wọ́n bá pa (ìmọ́lẹ̀) ìràwọ̀ rẹ́,

:9

àti nígbà tí wọ́n bá ṣí sánmọ̀ sílẹ̀ gbagada,

:10

àti nígbà tí wọ́n bá ku àwọn àpáta dànù,

:11

àti nígbà tí wọ́n bá fún àwọn Òjíṣẹ́ ní àsìkò láti kójọ (pẹ̀lú ìjọ wọn),

:12

ọjọ́ wo ni wọ́n so (àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí) rọ̀ fún ná?

:13

Fún ọjọ́ ìpínyà (láààrin àwọn ẹ̀dá) ni.

:14

Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ìpínyà?

:15

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.

:16

Ǹjẹ́ Àwa kò ti pa àwọn ẹni àkọ́kọ́ rẹ́ bí?

:17

Lẹ́yìn náà, A sì máa fi àwọn ẹni Ìkẹ́yìn tẹ̀lé wọn (nínú ìparun).

:18

Báyẹn ni A ó ti ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.

:19

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.

:20

Ṣé A kò ṣẹ̀dá yin láti inú omi lílẹ yẹpẹrẹ bí?

:21

Lẹ́yìn náà, A fi sínú àyè ààbò (ìyẹn, ilé-ọmọ)

:22

títí di gbèdéke àkókò kan tí A ti mọ̀ (ìyen, ọjọ́ ìbímọ).

:23

A sì ní ìkápá àti àyànmọ́ (lórí rẹ̀. Àwa sì ni) Olùkápá àti Olùpèbùbù ẹ̀dá tó dára.

:24

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.

:25

Ǹjẹ́ Àwa kò ṣe ilẹ̀ ní ohun tó ń kó ẹ̀dá jọ mọ́ra wọn;

:26

(ìyẹn) àwọn alààyè àti àwọn òkú?

:27

A sì fi àwọn àpáta gbagidi gíga-gíga sínú rẹ̀. A sì fún yín ní omi dídùn mu.

:28

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.

:29

Ẹ máa lọ sí ibi tí ẹ̀ ń pè ní irọ́.

:30

Ẹ máa lọ sí ibi èéfín ẹlẹ́ka mẹ́ta.

:31

Kì í ṣe ibòji tútù. Kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ìjòfòfò Iná.

:32

Dájúdájú (Iná náà) yóò máa ju ẹ̀tapàrà (rẹ̀ sókè tó máa dà) bí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì.

:33

(Ó máa dà) bí àwọn ràkúnmí aláwọ̀ omi ọsàn.

:34

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́

:35

Èyí ni ọjọ́ tí wọn kò níí sọ̀rọ̀.

:36

A kò sì níí yọ̀ǹda (ọ̀rọ̀ sísọ) fún wọn, áḿbọ̀sìbọ́sí pé wọ́n yóò mú àwáwí wá.

:37

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.

:38

Èyí ni ọjọ́ ìpínyà. Àwa yó sì kó ẹ̀yin àti àwọn ẹni àkọ́kọ́ jọ.

:39

Tí ẹ bá ní ète kan lọ́wọ́, ẹ déte sí Mi wò.

:40

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.

:41

Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù Allāhu yóò wà níbi ibòji àti àwọn omi ìṣẹ́lẹ̀rú,

:42

àti àwọn èso èyí tí wọ́n bá ń fẹ́.

:43

Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu pẹ̀lú ìgbádùn nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

:44

Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).

:45

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.

:46

Ẹ jẹ, kí ẹ sì gbádùn fún ìgbà díẹ̀. Dájúdájú ẹlẹ́ṣẹ̀ ni yín.

:47

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.

:48

Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé kí wọ́n kírun, wọn kò níí kírun.

:49

Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.

:50

Nígbà náà, ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀?1