Gbogbo Islam Library

75 - The Resurrection - Al-Qiyāmah

:1

Èmi (Allāhu) ń fi Ọjọ́ Àjíǹde búra.

:2

Mo tún ń fi ẹ̀mí tó máa dá ara rẹ̀ ní ẹ̀bi búra.

:3

Ṣé ènìyàn lérò pé A kò níí kó àwọn eegun rẹ̀ jọ ni?

:4

Bẹ́ẹ̀ ni A sì lágbára láti to eegun ọmọníka rẹ̀ dọ́gba

:5

Rárá ènìyàn fẹ́ máa ṣe aburú lọ bẹ́ẹ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ̀

:6

ni ó fi ń bèèrè pé: “Ìgbà wo ni Ọjọ́ Àjíǹde?”

:7

Nígbà tí ojú bá rí ìdààmú tó sì yà sílẹ̀ tí kò lè padé,

:8

àti (nígbà) tí òṣùpá bá wọ̀ọ̀kùn,

:9

àti (nígbà) tí wọ́n bá pa òòrùn àti òṣùpá pọ̀ mọ́ra wọn tí ìmọ́lẹ̀ méjèèjì pòóró,

:10

ènìyàn yóò wí ní ọjọ́ yẹn pé: “Níbo ni ibùsásí wà?”

:11

Rárá, kò sí ibùsásí.

:12

Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni ibùdúró ní ọjọ́ yẹn.

:13

Wọ́n máa fún ènìyàn ní ìró ní ọjọ́ yẹn nípa ohun tó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun tó fi kẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀).

:14

Ṣebí ènìyàn dá ara rẹ̀ mọ̀,

:15

ìbáà mú àwọn àwáwí rẹ̀ wá.

:16

Má ṣe gbé ahọ́n rẹ sí ìmísí láti kánjú ké e.

:17

Dájúdájú Àwa l’A máa ṣe àkójọ rẹ̀ (sínú ọkàn rẹ) àti kíké rẹ̀.

:18

Nígbà tí A bá ń ké e (fún ọ), kí o sì máa tẹ̀lé kíké rẹ̀.

:19

Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l’A máa ṣe àlàyé rẹ̀ fún ọ.

:20

Kò rí bẹ́ẹ̀, bí kò ṣe pé, ẹ nífẹ̀ẹ́ ayé ni.

:21

Ẹ sì ń gbé ọ̀run jù sílẹ̀.

:22

Àwọn ojú kan ní ọjọ́ yẹn yóò tutù (fún ìdùnnú).

:23

Olúwa wọn ni wọn yóò máa wò.

:24

Àwọn ojú kan ní ọjọ́ yẹn sì máa bàjẹ́.

:25

(Ojú náà) yóò mọ̀ dájú pé wọ́n máa fi aburú kan òhun.

:26

Kò rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí ẹ̀mí bá dé gògòńgò.

:27

A sì máa sọ pé: “Ǹjẹ́ olùpọfọ̀ kan wà bí (tí ó máa pọfọ̀ láti gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú)?

:28

Ó sì máa dá a lójú pé dájúdájú ìpínyà ayé ti dé.

:29

Ojúgun yó sì lọ́mọ́ ojúgun.

:30

Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì ni wíwa ẹ̀dá lọ ní ọjọ́ yẹn.

:31

Kò kúkú gba òdodo gbọ́, kò sì kírun.

:32

Ṣùgbọ́n ó pe òdodo ní irọ́. Ó sì kẹ̀yìn sí i.

:33

Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ń ṣe fáàrí.

:34

Ègbé ni fún ọ, ègbé ni sẹ́.

:35

Lẹ́yìn náà, ègbé ni fún ọ, ègbé sì ni fún ọ sẹ́.

:36

Ṣé ènìyàn lérò pé A máa fi òun sílẹ̀ lásán ni?

:37

Ṣé kò ti jẹ́ àtọ̀ mọnī tí wọ́n dà jáde sínú àpòlùkẹ́ ni?

:38

Lẹ́yìn náà, ó di ẹ̀jẹ̀ dídì. (Allāhu) sì ṣẹ̀dá (rẹ̀). Ó sì ṣe é tó dọ́gba jálẹ̀ léèyàn.

:39

(Allāhu) sì ṣe ìran méjì jáde láti ara rẹ̀, akọ àti abo.

:40

Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó ṣe ìyẹn kò níí ní agbára láti jí àwọn òkú dìde bí?