Gbogbo Islam Library

52 - The Mount - Aţ-Ţūr

:1

Allāhu fi àpáta Tūr búra.

:2

Ó tún fi Tírà tí wọ́n kọ n̄ǹkan sínú rẹ̀ búra .

:3

(Wọ́n kọ̀ ọ́) sínú n̄ǹkan ìkọ̀wé tí wọ́n tẹ́ ojú rẹ̀ sílẹ̀.

:4

Allāhu fi Ilé tí àwọn mọlāika ń wọnú rẹ̀ ní ojoojúmọ́ nínú sánmọ̀ búra.

:5

Ó tún fi àjà tí wọ́n gbé sókè (ìyẹn, sánmọ̀) búra.

:6

Ó tún fi agbami odò tí wọ́n máa mú iná jáde nínú rẹ̀ búra.

:7

Dájúdájú ìyà Olúwa rẹ máa ṣẹlẹ̀.

:8

Kò sí ẹni tí ó máa dènà rẹ̀.

:9

(Ó máa ṣẹlẹ̀) ní ọjọ́ tí sánmọ̀ máa mì tìtì tààrà.

:10

àpáta sì máa rìn lọ dànù.

:11

Ní ọjọ́ yẹn, ègbé ni fún àwọn tó pe òdodo ní irọ́,

:12

àwọn tí wọ́n wà nínú ìsọkúsọ, tí wọ́n ń ṣeré.

:13

(Rántí) ọjọ́ tí wọn yóò máa tì wọ́n lọ́ sínú iná Jahanamọ ní ìtìkutì.

:14

Èyí ni Iná náà tí ẹ̀ ń pè ní irọ́.

:15

Ṣé idán ni èyí ni tàbí ẹ̀yin kò ríran?

:16

Ẹ wọ inú rẹ̀ lọ. Ẹ fara dà á tàbí ẹ kò fara dà á, bákan náà ni fún yín. Ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ ni A óò fi san yín ní ẹ̀san.

:17

Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) máa wà nínú àwọn Ọgbà àti ìdẹ̀ra.

:18

Wọn yóò máa jẹ ìgbádùn pẹ̀lú ohun tí Olúwa wọn fún wọn. Àti pé (Allāhu) yóò ṣọ́ wọn kúrò níbi ìyà iná Jẹhīm.

:19

Ẹ máa jẹ, ẹ máa mu ní gbẹdẹmukẹ nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

:20

Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú sórí àwọn ibùsùn tí wọ́n tò ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. A sì máa fún wọn ní àwọn ìyàwó ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́.

:21

Àti pé àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn tún tẹ̀lé wọn nínú ìgbàgbọ́ òdodo, A máa da àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn pọ̀ mọ́ wọn. A kò sì níí dín kiní kan kù nínú iṣẹ́ wọn. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa dúró fún ohun tó ṣe níṣẹ́.

:22

A máa fún wọn ní àlékún èso àti ẹran tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí.

:23

Wọn yó sì máa gba ife ọtí mu láààrin ara wọn nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Kò sí ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ àti ìwà ẹ̀ṣẹ̀ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.

:24

Àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ wọn yó sì máa lọ bọ̀ láààrin wọn. (Wọ́n) dà bí àlúùúlù (òkúta olówó-iye-bíye) tí wọ́n fi pamọ́ sínú apó rẹ̀.

:25

Apá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, wọn yó sì máa bèèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ara wọn.

:26

Wọn yóò sọ pé: “Dájúdájú tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ àwa máa ń páyà láààrin àwọn ènìyàn wa.

:27

Ṣùgbọ́n Allāhu ṣàánú wa. Ó sì là wá kúrò níbi ìyà Iná.

:28

Dájúdájú àwa máa ń pè É tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olóore, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”

:29

Nítorí náà, ṣèrántí. Ìwọ kì í ṣe adábigba tàbí wèrè lórí ìdẹ̀ra Olúwa rẹ.

:30

Tàbí wọ́n ń wí pé: “Eléwì kan tí à ń retí àpadàsí aburú fún ni.”

:31

Sọ pé: “Ẹ máa retí. Dájúdájú èmi náà wà pẹ̀lú yín nínú àwọn olùretí.

:32

Tàbí ọpọlọ wọn ló ń pa wọ́n láṣẹ èyí ni? Tàbí ìjọ alákọyọ ni wọ́n ni?

:33

Tàbí wọ́n ń wí pé: “Ó dá (al-Ƙur’ān) hun fúnra rẹ̀ ni.” Rárá o, wọn kò gbàgbọ́ ni.

:34

Kí àwọn náà mú ọ̀rọ̀ kan bí irú rẹ̀ wá tí wọ́n bá jẹ́ olódodo.

:35

Tàbí wọ́n ṣẹ̀dá wọn láì sí Aṣẹ̀dá? Tàbí àwọn ni wọ́n ṣẹ̀dá ara wọn ni?

:36

Tàbí àwọn ni wọ́n ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Rárá o, wọn kò màmọ̀ dájú ni.

:37

Tàbí lọ́dọ̀ wọn ni àwọn ilé ọrọ̀ Olúwa rẹ wà? Tàbí àwọn ni olùborí?

:38

Tàbí wọ́n ní àkàbà kan tí wọ́n ń fi gbọ́rọ̀ (nínú sánmọ̀)? Kí ẹni tí ó ń bá wọn gbọ́ ọ̀rọ̀ mú ẹ̀rí tó yanjú wá?

:39

Tàbí àwọn ọmọbìnrin ni tiRẹ̀, àwọn ọmọkùnrin sì ni tiyín?

:40

Tàbí ò ń bèèrè owó-ọ̀yà kan lọ́wọ́ wọn, ni gbèsè fi wọ̀ wọ́n lọ́rùn?

:41

Tàbí ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ wà lọ́dọ̀ wọn, tí wọ́n sì ń kọ ọ́ sílẹ̀?

:42

Tàbí wọ́n ń gbèrò ète kan ni? Nígbà náà, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àwọn l’ó máa f’orí kó ète náà.

:43

Tàbí wọ́n ní ọlọ́hun kan lẹ́yìn Allāhu ni? Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.

:44

Tí wọ́n bá rí apá kan nínú sánmọ̀ tó ya lúlẹ̀, wọ́n á wí pé: “Ẹ̀ṣújò rẹgẹdẹ ni (wọn kò níí gbàgbọ́).”

:45

Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ títí wọn yóò fi bá ọjọ́ wọn tí wọn máa pa wọ́n sínú rẹ̀ pàdé.

:46

Ọjọ́ tí ète wọn kò níí fi kiní kan rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀. A kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.

:47

Àti pé dájúdájú ìyà kan ń bẹ fún àwọn tó ṣàbòsí yàtọ̀ sí (ìyà ọ̀run) yẹn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.

:48

Ṣe sùúrù fún ìdájọ́ Olúwa Rẹ, dájúdájú ìwọ wà ní ojútó Wa. Kí ó sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Olúwa rẹ nígbà tí o bá fẹ́ dìde.1

:49

Àti pé ní alẹ́ àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá kúrò níta tán ṣàfọ̀mọ́ fún Un.