Gbogbo Islam Library

51 - The Winnowing Winds - Adh-Dhāriyāt

:1

Allāhu fi atẹ́gùn tó ń tu erùpẹ̀ jáde nílẹ̀ ní títu-jáde tààrà búra.

:2

Allāhu fi àwọn ẹ̀ṣújò tó ru òjò tó wúwo búra.

:3

Allāhu fi àwọn ọkọ̀ ojú-omi tó ń rìn pẹ̀lú ìrọ̀rùn búra.

:4

Allāhu fi àwọn mọlāika tó ń pín n̄ǹkan tí Ó ti pín fún ẹ̀dá búra.

:5

Òdodo mà ni ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún yín.

:6

Àti pé dájúdájú ẹ̀san iṣẹ́ máa ṣẹlẹ̀.

:7

Allāhu tún fi sánmọ̀ ọlọ́ṣọ̀ọ́ tó gún régé búra.

:8

Dájúdájú ẹ̀yin wà lórí ọ̀rọ̀ tó ń takora wọn (nípa al-Ƙur’ān).

:9

Ẹni tí wọ́n ń ṣẹ́ lórí kúrò níbi al-Ƙur’ān ni ẹni tí Wọ́n ti ṣẹ́ lórí kúrò níbẹ̀ (láti inú Laohul-Mahfūṭḥ).

:10

Ègbé ni fún àwọn òpùrọ́;

:11

àwọn tí wọ́n wà nínú àìmọ̀kan tó gbópọn tí wọ́n ti gbàgbéra.

:12

tí wọ́n ń bèèrè ìgbà tí Ọjọ́ Ẹ̀san máa ṣẹlẹ̀.

:13

Ní ọjọ́ náà sì ni wọn yóò máa fi Iná jẹ wọ́n níyà.

:14

Ẹ tọ́ ìyà yín wò. Èyí ni n̄ǹkan tí ẹ ti ń wá pẹ̀lú ìkánjú.

:15

Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) yóò wà nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra pẹ̀lú àwọn omi odò ìṣẹ́lẹ̀rú (ní ìsàlẹ̀ rẹ̀).

:16

Wọn yóò máa gba n̄ǹkan tí Olúwa wọn bá fún wọn. Dájúdájú wọ́n ti jẹ́ olùṣe-rere ṣíwájú ìyẹn.

:17

Wọ́n máa ń sun oorun díẹ̀ nínú òru.

:18

Wọ́n máa ń tọrọ àforíjìn ní àfẹ̀mọ́júmọ́.

:19

Nínú dúkìá wọn, wọ́n ní ojúṣe tí wọ́n ń ṣe fún alágbe àti ẹni tí A ṣe arísìkí ní èèwọ̀ fún.

:20

Àwọn àmì wà ní orí ilẹ̀ fún àwọn alámọ̀dájú.

:21

Nínú ẹ̀mí ara yín gan-an (àmì ìyanu wà nínú rẹ̀). Ṣé ẹ kò ríran ni?

:22

Arísìkí yín àti ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún yín wà nínú sánmọ̀.

:23

Nítorí náà, Mó fi Olúwa sánmọ̀ àti ilẹ̀ búra, dájúdájú òdodo ni (ọ̀rọ̀ náà) gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ òdodo pé ẹ̀ ń fẹnu sọ̀rọ̀.

:24

Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ àwọn àlejò (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, àwọn alápọ̀n-ọ́nlé, ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?

:25

(Rántí) nígbà tí wọ́n wọlé tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì sọ pé: “Àlàáfíà (fún ọ).” Òun náà sọ pé: “Àlàáfíà (fún yín), ẹ̀yin àjòjì ènìyàn.”

:26

Ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará ilé rẹ̀, ó sì dé pẹ̀lú ọmọ màálù tó ní ọ̀rá (tí wọ́n ti yangbẹ).

:27

Ó gbé e súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn. Ó sì sọ pé: “Ṣé ẹ kò níí jẹun ni?”

:28

Nígbà náà, ìbẹ̀rù wọn sì mú un. Wọ́n sọ pé: “Má ṣe páyà.” Wọ́n sì fún un ní ìró ìdùnnú nípa bíbí ọmọkùnrin kan tí ó máa ní ìmọ̀.

:29

Nígbà náà, ìyàwó rẹ̀ wọlé pẹ̀lú igbe, ó sì gbára rẹ̀ lójú, ó sọ pé: “Arúgbó, àgàn (mà ni mí)!”

:30

Wọ́n sọ pé: “Báyẹn ni Olúwa rẹ sọ. Dájúdájú Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.”

:31

(Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “Kí tún ni ọ̀rọ̀ tí ẹ bá wá, ẹ̀yin Òjíṣẹ́?”

:32

Wọ́n sọ pé: “Dájúdájú Wọ́n rán wa níṣẹ́ sí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni

:33

nítorí kí á lè fi òkúta amọ̀ (sísun) ránṣẹ́ sí wọn.

:34

Wọ́n ti fi àmì sí i lára lọ́dọ̀ Olúwa rẹ fún àwọn alákọyọ.”

:35

Nítorí náà, A mú àwọn tó jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo jáde kúrò nínú (ìlú náà).

:36

A kò sì rí nínú (ìlú náà) yàtọ̀ sí ilé kan tó jẹ́ ti àwọn mùsùlùmí.

:37

A sì fi àmì kan sílẹ̀ nínú (ìlú náà) fún àwọn tó ń páyà ìyà ẹlẹ́ta-eléro.

:38

(Àmì tún wà) lára (Ànábì) Mūsā. Nígbà tí A fi ẹ̀rí pọ́nńbélé rán an níṣẹ́ sí Fir‘aon.

:39

Ṣùgbọ́n ó lo gbogbo agbára rẹ̀ láti kẹ̀yìn sí òdodo. Ó sì wí pé: “Òpìdán tàbí wèrè kan (nìyí).”

:40

Nítorí náà, A mú òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀. A sì jù wọ́n sínú agbami odò nígbà tí ó jẹ́ alábùkù.

:41

(Àmì tún wà) lára ìjọ ‘Ād. (Rántí) nígbà tí A rán atẹ́gùn ìparun sí wọn.

:42

Kò fi kiní kan tó fẹ́ sí lára sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ àfi kí ó sọ ọ́ di n̄ǹkan tó kẹfun.1

:43

(Àmì tún wà) lára ìjọ Thamūd. (Rántí) nígbà tí A sọ fún wọn pé: “Ẹ jayé fún ìgbà díẹ̀ ná.”

:44

Wọ́n ṣègbéraga sí àṣẹ Olúwa wọn. Nítorí náà, iná láti ojú sánmọ̀ gbá wọn mú; wọ́n sì ń wò bọ̀ọ̀.

:45

Wọn kò lè dìde nàró. Wọn kò sì lè ran ara wọn lọ́wọ́.

:46

Àti ìjọ Nūh tí ó ṣíwájú (wọn), dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ arúfin.

:47

Àti pé sánmọ̀, A mọ ọ́n (sí òkè yín) pẹ̀lú agbára. Dájúdájú Àwa sì ni Alágbára (tí a mú un tóbi).

:48

Àti ilẹ̀, A ṣe é ní ìtẹ́. (Àwa sì ni) olùtẹ́-ilẹ̀ sílẹ̀ tó dára.

:49

Àti pé gbogbo n̄ǹkan ni A ṣẹ̀dá rẹ̀ ní oríṣi méjì-méjì nítorí kí ẹ lè lo ìrántí.1

:50

Nítorí náà, ẹ sá lọ sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípa ìronúpìwàdà). Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fún yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

:51

Ẹ má ṣe mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fún yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

:52

Báyẹn ni (ọ̀rọ̀ ṣe rí)! Òjíṣẹ́ kan kò wá bá àwọn tó ṣíwájú wọn àfi kí wọ́n wí pé: “Òpìdán tàbí wèrè ni.”

:53

Ṣé wọn sọ àsọọ́lẹ̀ nípa rẹ̀ láààrin ara wọn ni? Rárá o! Ìjọ olùtayọ-ẹnu-ààlà ni wọ́n ni.

:54

Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn ná. Ìwọ kì í ṣe ẹni tí A máa bá wí.

:55

Ṣèrántí nítorí pé, dájúdájú ìrántí máa wúlò fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

:56

Àti pé Èmi kò ṣẹ̀dá àlùjànnú àti ènìyàn bí kò ṣe pé kí wọ́n lè jọ́sìn fún Mi.

:57

Èmi kò gbèrò arísìkí kan láti ọ̀dọ̀ wọn. Èmi kò sì gbèrò pé kí wọ́n máa bọ́ Mi.

:58

Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùpèsè, Alágbára líle.

:59

Dájúdájú ìpín ìyà tí ó máa jẹ àwọn tó ṣàbòsí (wọ̀nyí) ni irú ìpín ìyà tí ó jẹ ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ (irú) wọn. Nítorí náà, kí wọ́n má ṣe kán Mi lójú (nípa ìyà wọn).

:60

Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ní ọjọ́ wọn tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.