1
Sọ fún mi nípa ẹni tó ń pe Ọjọ́ Ẹ̀san ní irọ́!
2
Ìyẹn ni ẹni tó ń lé ọmọ-òrukàn dànù.
3
Kò sì níí gbìyànjú láti bọ́ mẹ̀kúnnù.
4
Ègbé ni fún àwọn (mùnááfìkí) tó ń kírun;1
5
àwọn tó ń gbàgbé láti kírun wọn ní àsìkò rẹ̀;
6
àwọn tó ń ṣe ṣekárími;
7
àti pé wọ́n ń hánnà ohun èlò (fún àwọn ènìyàn).