Gbogbo Islam Library

69 - The Reality - Al-Ĥāqqah

:1

Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà!

:2

Kí ni Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà?

:3

Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà?

:4

Àwọn ìjọ Thamūd àti ìjọ ‘Ād pe Àjíǹde (ajámọláya bí àrá) ní irọ́.1

:5

Ní ti ìjọ Thamūd, wọ́n fi igbe tó tayọ ẹnu-ààlà pa wọ́n rẹ́.

:6

Ní ti ìjọ ‘Ād, wọ́n fi atẹ́gùn líle tó tayọ ẹnu-ààlà pa wọ́n rẹ́.

:7

Ó dẹ ẹ́ sí wọn fún òru méje àti ọ̀sán mẹ́jọ láì dáwọ́ dúró. O sì máa rí ìjọ náà tí wọ́n ti kú sínú rẹ̀ bí ẹni pé kùkùté igi dàbínù tó ti luhò nínú ni wọ́n.1

:8

Ǹjẹ́ o rí ẹnì kan nínú wọn tó ṣẹ́ kù bí?

:9

Fir‘aon àti àwọn tó ṣíwájú rẹ̀ àti àwọn ìlú tí wọ́n dojú rẹ̀ bolẹ̀ dé pẹ̀lú àwọn àṣìṣe.

:10

Wọ́n yapa Òjíṣẹ́ Olúwa wọn. Ó sì gbá wọn mú ní ìgbámú tóléken̄kà.

:11

Dájúdájú nígbà tí omi tayọ ẹnu-ààlà. A gbe yín gun ọkọ̀ ojú-omi.

:12

Nítorí kí Á lè fi ṣe ìrántí fún yín àti nítorí kí etí tó ń ṣọ́ n̄ǹkan lè ṣọ́ ọ.

:13

Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún ikú ní fífọn ẹyọ kan,

:14

tí wọ́n gbé ilẹ̀ àti àpáta sókè, tí wọ́n sì rún méjèèjì wómúwómú ní rírún ẹ̀ẹ̀ kan,

:15

ní ọjọ́ yẹn ni Ìṣẹ̀lẹ̀ máa ṣẹlẹ̀.

:16

Àti pé sánmọ̀ yó fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Ó sì máa fúyẹ́ gẹgẹ ní ọjọ́ yẹn.

:17

Àwọn mọlāika sì máa wà ní àwọn ẹ̀gbẹ́ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àti pé ní ọjọ́ yẹn, lókè wọn, àwọn (mọlāika) mẹ́jọ ni wọ́n máa ru Ìtẹ́ Olúwa rẹ.

:18

Ní ọjọ́ yẹn, wọn yóò máa ṣẹ́rí yín wá (fún ìṣírò-iṣẹ́). Kò sì níí sí àṣírí yín kan tó máa pamọ́ (fún Wa).

:19

Nítorí náà, ní ti ẹni tí wọ́n bá fún ní tírà rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ó máa sọ pé: “Ẹ gbà, ẹ ka tírà mi wò.

:20

Dájúdájú èmi ti mọ àmọ̀dájú pé dájúdájú èmi yóò bá ìṣírò-iṣẹ́ mi pàdé.”

:21

Nítorí náà, ó máa wà nínú ìṣẹ̀mí tó máa yọ́nú sí

:22

nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra gíga.

:23

Àwọn èso rẹ̀ (sì) máa wà ní àrọ́wọ́tó.

:24

Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu pẹ̀lú ìgbàdún nítorí ohun tí ẹ tì síwájú nínú àwọn ọjọ́ tí ó ti ré kọjá.

:25

Ní ti ẹni tí wọ́n bá sì fún ní tírà rẹ̀ ní ọwọ́ òsì rẹ̀, ó máa wí pé: “Háà! Kí wọ́n sì má fún mi ni tírà mi!1

:26

Àti pé kí èmi sì má mọ ohun tí ìṣírò-iṣẹ́ mi jẹ́.

:27

Háà! Kí ikú sì jẹ́ òpin (ọ̀rọ̀ ẹ̀dá).

:28

Dúkìá mi kò sì rọ̀ mí lọ́rọ̀.

:29

Agbára mi sì ti parun.”

:30

Ẹ mú un, kí ẹ dè é ní ọwọ́ mọ́ ọrùn.

:31

Lẹ́yìn náà, inú iná Jẹhīm ni kí ẹ mú un wọ̀.

:32

Lẹ́yìn náà, inú ẹ̀wọ̀n tí gígùn rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin gígùn thar‘uni kí ẹ kì í sí.

:33

Dájúdájú òun kì í gbàgbọ́ nínú Allāhu, Atóbi.

:34

Kì í sì gba ènìyàn níyànjú láti bọ́ àwọn mẹ̀kúnnù.

:35

Nítorí náà, kò níí sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan fún un níbí yìí ní òní.

:36

Kò sì níí sí oúnjẹ kan (fún un) bí kò ṣe (oúnjẹ) àwọnúwẹ̀jẹ̀.

:37

Kò sí ẹni tí ó máa jẹ ẹ́ bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.

:38

Nítorí náà, Èmi ń fi ohun tí ẹ̀ ń fojú rí búra

:39

àti ohun tí ẹ ò fojú rí.

:40

Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé.1

:41

Kì í ṣe ọ̀rọ̀ eléwì. Ohun tí ẹ gbàgbọ́ kéré púpọ̀.

:42

Kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ adábigba. Díẹ̀ lẹ̀ ń lò nínú ìrántí.

:43

Wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

:44

Tí ó bá jẹ́ pé (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ) dá àdápa apá kan ọ̀rọ̀ náà mọ́ Wa ni,

:45

Àwa ìbá gbá a mú lọ́wọ́ ọ̀tún.

:46

Lẹ́yìn náà, Àwa ìbá já isan ọrùn rẹ̀.

:47

Kò sì sí ẹnì kan nínú yín tí ó máa gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ (Wa).

:48

Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni ìrántí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).

:49

Dájúdájú Àwa sì mọ̀ pé àwọn tó ń pe al-Ƙur’ān ní irọ́ wà nínú yín.

:50

Dájúdájú al-Ƙur’ān máa jẹ́ àbámọ̀ ńlá fún àwọn aláìgbàgbọ́.

:51

Dájúdájú al-Ƙur’ān ni òdodo tó dájú.

:52

Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa Rẹ, Atóbi.