Gbogbo Islam Library

67 - The Sovereignty - Al-Mulk

:1

Ìbùkún ni fún Ẹni tí gbogbo ìjọba wà ní Ọwọ́ Rẹ̀. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

:2

Ẹni tí Ó dá ikú àti ìṣẹ̀mí nítorí kí ó lè dan yín wò; èwo nínú yín l’ó máa ṣe iṣẹ́ rere jùlọ. Òun sì ni Alágbára, Aláforíjìn.

:3

Ẹni tí Ó dá àwọn sánmọ̀ méje ní ìpele ìpele. O ò lè rí àìgúnrégé kan lára ẹ̀dá Àjọkẹ́-ayé. Nítorí náà, wò ó padà, ǹjẹ́ o rí ojú sísán kan (lára sánmọ̀)?

:4

Lẹ́yìn náà, wò ó padà ní ẹ̀ẹ̀ mejì, kí ojú rẹ padà sí ọ̀dọ̀ rẹ pẹ̀lú ìyẹpẹrẹ. Ó sì máa káàárẹ̀.

:5

Dájúdájú A ti fi (àwọn ìràwọ̀ tó ń tànmọ́lẹ̀ bí) àtùpà ṣe sánmọ̀ ilé ayé ní ọ̀ṣọ́. A tún ṣe wọ́n ni ẹ̀ta-ìràwọ̀ tí wọ́n ń jù mọ́ àwọn èṣù. A sì pèsè ìyà Iná tó ń jó sílẹ̀ dè wọ́n.

:6

Ìyà iná Jahanamọ sì wà fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́. Ìkángun náà sì burú.

:7

Nígbà tí wọ́n bá jù wọ́n sínú rẹ̀, wọn yóò máa gbọ́ kíkùn rẹ̀, tí ó sì máa ru sókè.

:8

Iná máa fẹ́ẹ̀ pínra rẹ̀ láti ara ìbínú. Ìgbàkígbà tí wọ́n bá ju ìjọ kan sínú rẹ̀, àwọn ẹ̀ṣọ́ Iná yóò máa bi wọ́n léèrè pé: “Ǹjẹ́ olùkìlọ̀ kan kò wá ba yín bí?”

:9

Wọn yóò wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, dájúdájú olùkìlọ̀ kan ti wá bá wa, ṣùgbọ́n a pè é ní òpùrọ́. A sì wí pé Allāhu kò sọ n̄ǹkan kan kalẹ̀. Kí ni ẹ̀yin bí kò ṣe pé ẹ wà nínú ìṣìnà tó tóbi.”

:10

Wọ́n tún wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé a gbọ́ràn ni tàbí pé a ṣe làákàyè ni, àwa kò níí wà nínú èrò inú Iná tó ń jó.”

:11

Wọ́n sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Nítorí náà, ìjìnnà sí ìkẹ́ Allāhu yó wà fún àwọn èrò inú Iná tó ń jó.

:12

Dájúdájú àwọn tó ń páyà Olúwa wọn ní ìkọ̀kọ̀, àforíjìn àti ẹ̀san tó tóbi ń bẹ fún wọn.

:13

Ẹ wí ọ̀rọ̀ yín ní jẹ́ẹ́jẹ́ tàbí ẹ wí i sókè, dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa ohun tó wà nínú àwọn igbá-àyà ẹ̀dá.

:14

Ṣé kò mọ Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá ni?Òun sì ni Aláàánú, Alámọ̀tán.

:15

Òun ni Ẹni tí Ó rọ ilẹ̀ fún yín. Nítorí náà, ẹ rìn ní àwọn agbègbè rẹ̀ káàkiri, kí ẹ sì jẹ nínú arísìkí Rẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àjíǹde ẹ̀dá wà.

:16

Ṣé ẹ fọkànbalẹ̀ sí Ẹni tí Ó wà ní (òkè) sánmọ̀ pé kò lè jẹ́ kí ilẹ̀ gbe yín mì? Nígbà náà, ilẹ̀ yó sì máa mì tìtì.

:17

Tàbí ẹ̀ fọkànbalẹ̀ sí Ẹni tí Ó wà ní (òkè) sánmọ̀ pé kò lè fi òkúta iná ránṣẹ́ si yín ni? Nígbà náà, ẹ sì máa mọ bí ìkìlọ̀ Mi ti rí.1

:18

Àwọn tó ṣíwájú wọn kúkú pe òdodo ní irọ́. Báwo sì ni bí Mo ṣe (fi ìyà) kọ (aburú fún wọn) ti rí!

:19

Ṣé wọn kò rí àwọn ẹyẹ tí ó wà ní òkè wọn, tí (wọ́n) ń na ìyẹ́ apá (wọn), tí wọ́n sì ń pa á mọ́ra? Kiní kan kò mú wọn dúró (sínú òfurufú) àfi Àjọkẹ́-ayé. Dájúdájú Òun sì ni Olùríran nípa gbogbo n̄ǹkan.

:20

Ta ni ẹni tí ó máa jẹ́ ọmọ ogun fún yín, tí ó máa ràn yín lọ́wọ́ lẹ́yìn Àjọkẹ́-ayé? (Nínú) kí ni àwọn aláìgbàgbọ́ wà bí kò ṣe nínú ẹ̀tàn.

:21

Ta ni ẹni tí ó máa pèsè fún yín tí Ó bá dá arísìkí Rẹ̀ dúró? Ńṣe ni wọ́n ń ṣorí kunkun sí i nínú ìgbéraga àti sísá fún òdodo.

:22

Ǹjẹ́ ẹni tó ń rìn ní ìdojúbolẹ̀ l’ó mọ̀nà jùlọ ni tàbí ẹni tó ń rìn sàn án lójú ọ̀nà tààrà?

:23

Sọ pé: “Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín. Ó sì ṣe ìgbọ́rọ̀, ìríran àti àwọn ọkàn fún yín. Ọpẹ́ tí ẹ̀ ń dá sì kéré púpọ̀.”

:24

Sọ pé: “Òun ni Ẹni tí Ó da yín sí orí ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò ko yín jọ sí.”

:25

Wọ́n ń wí pé: “Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”

:26

Sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Allāhu nìkan ni ìmọ̀ (nípa) rẹ̀ wà. Èmi kàn jẹ́ olùkìlọ̀ pọ́nńbélé ni.”

:27

Nígbà tí wọ́n bá rí i tó súnmọ́, ojú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yóò korò wá fún ìbànújẹ́. A ó sì sọ fún wọn pé: “Èyí ni ohun tí ẹ̀ ń pè.”

:28

Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi, tí Allāhu bá pa èmi àti àwọn tó wà pẹ̀lú mi rẹ́, tàbí tí Ó bá kẹ́ wa (ṣé ẹ lè dí I lọ́wọ́ ni?) Nítorí náà, ta ni ó máa gba àwọn aláìgbàgbọ́ là nínú ìyà ẹlẹ́ta-eléro?

:29

Sọ pé: “Òun ni Àjọkẹ́-ayé. Àwa gbà Á gbọ́. Òun sì la gbáralé. Láìpẹ́ ẹ máa mọ ta ni ó wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.”

:30

Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi, tí omi yín bá gbẹ wá, ta ni ẹni tí ó máa mú omi tó ń ṣàn wá fún yín?”1