Gbogbo Islam Library

64 - The Mutual Disillusion - At-Taghābun

:1

Ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ ń ṣe àfọ̀mọ́ fún Allāhu. TiRẹ̀ ni ìjọba. TiRẹ̀ sì ni ẹyìn. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

:2

Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín. Aláìgbàgbọ́ wà nínú yín. Onígbàgbọ́ òdodo sì wà nínú yín. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

:3

Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Ó ya àwòrán yín. Ó sì ṣe àwọn àwòrán yín dáradára. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.

:4

Ó mọ ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó sì mọ ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́ àti ohun tí ẹ̀ ń ṣàfi hàn rẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá.

:5

Ṣé ìró àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ní ìṣáájú kò tí ì dé ba yín ni? Nítorí náà, wọ́n tọ́ ìyà ọ̀ràn wọn wò. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.

:6

Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ wọn ń wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú. Wọ́n sì wí pé: “Ṣé abara l’ó máa fi ọ̀nà mọ̀ wá?” Nítorí náà, wọ́n ṣàì gbàgbọ́. Wọ́n sì pẹ̀yìndà (sí òdodo). Allāhu sì rọrọ̀ láì sí àwọn. Àti pé Allāhu ni Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn.

:7

Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ lérò pé A ò níí gbé wọn dìde. Sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, mo fi Olúwa mi búra, dájúdájú Wọn yóò gbe yín dìde. Lẹ́yìn náà, Wọn yóò fún yín ní ìró ohun tí ẹ ṣe níṣẹ́. Ìyẹn sì jẹ́ ìrọ̀rùn fún Allāhu.”

:8

Nítorí náà, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti ìmọ́lẹ̀ tí A sọ̀kalẹ̀. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

:9

Ní ọjọ́ tí (Allāhu) yóò ko yín jọ fún ọjọ́ àkójọ. Ìyẹn ni ọjọ́ èrè àti àdánù.Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba Allāhu gbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, (Allāhu) yóò pa àwọn àṣìṣe rẹ̀ rẹ́ fún un. Ó sì máa mú un wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá.

:10

Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún pe àwọn āyah Wa ní irọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ìkángun náà sì burú.

:11

Àdánwò kan kò lè ṣẹlẹ̀ àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ nínú Allāhu ní òdodo, Allāhu máa fi ọkàn rẹ̀ mọ̀nà.Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.

:12

Kí ẹ tẹ̀lé ti Allāhu. Kí ẹ sì tẹ̀lé ti Òjíṣẹ́. Tí ẹ bá gbúnrí, ìkede ẹ̀sìn tó yanjú ni ojúṣe Òjíṣẹ́ Wa.

:13

Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Allāhu sì ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé.

:14

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú ọ̀tá wà fún yín nínú àwọn ìyàwó yín àti àwọn ọmọ yín. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra fún wọn. Tí ẹ bá ṣàmójúkúrò, tí ẹ ṣàfojúfò, tí ẹ sì ṣàforíjìn (fún wọn), dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

:15

Ìfòòró ni àwọn dúkìá yín àti àwọn ọmọ yín. Allāhu sì ni ẹ̀san ńlá wà ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

:16

Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu bí ẹ bá ṣe lágbára mọ. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ (Allāhu), ẹ tẹ̀lé e, kí ẹ sì náwó (fún ẹ̀sìn Rẹ̀) lóore jùlọ fún ẹ̀mí yín. Ẹnikẹ́ni tí A bá ṣọ́ níbi ahun àti ọ̀kánjúà inú ẹ̀mí rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olùjèrè.

:17

Tí ẹ bá yá Allāhu ní dúkìá tó dára, Ó máa ṣàdìpèlé rẹ̀ fún yín. Ó sì máa foríjìn yín. Allāhu sì ni Ọlọ́pẹ́ Aláfaradà,

:18

Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.