Gbogbo Islam Library

44 - The Smoke - Ad-Dukhān

:1

Hā mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)1

:2

(Allāhu) fi Tírà tó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá búra.

:3

Dájúdájú Àwa sọ̀ ọ́ kalẹ̀ nínú òru ìbùkún.Dájúdájú Àwa ń jẹ́ Olùkìlọ̀.

:4

Nínú òru náà ni wọ́n ti máa yanjú gbogbo ọ̀rọ̀ tí kò níí tàsé (lórí ẹ̀dá).

:5

Àṣẹ kan ni láti ọ̀dọ̀ Wa. Dájúdájú Àwa l’À ń rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́.

:6

Ìkẹ́ kan ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

:7

Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin méjèèjì tí ẹ̀yin bá jẹ́ alámọ̀dájú.

:8

Kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́.

:9

Síbẹ̀, wọ́n sì wà nínú iyèméjì, tí wọ́n ń ṣeré.

:10

Nítorí náà, máa retí ọjọ́ tí sánmọ̀ yóò mú èéfín pọ́nńbélé wá.

:11

Ó máa bo àwọn ènìyàn mọ́lẹ̀. Èyí ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro.

:12

(Àwọn ènìyàn yóò wí pé): Olúwa wa, gbé ìyà náà kúrò fún wa, dájúdájú àwa yóò gbàgbọ́ ní òdodo.

:13

Báwo ni ìrántí ṣe lè wúlò fún wọn (lásìkò ìyà)? Òjíṣẹ́ pọ́nńbélé kúkú ti dé bá wọn.

:14

náà, wọ́n gbúnrí kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. Wọ́n sì wí pé: “Wèrè tí àwọn ènìyàn kan ń kọ́ ní ẹ̀kọ́ ni.”

:15

Dájúdájú Àwa máa gbé ìyà náà kúrò fún ìgbà díẹ̀. Dájúdájú ẹ̀yin yóò tún padà (sínú àìgbàgbọ́).

:16

Ọjọ́ tí A óò gbá (wọn mú) ní ìgbámú tó tóbi jùlọ; dájúdájú Àwa yóò gba ẹ̀san ìyà (lára wọn).

:17

Dájúdájú A dán àwọn ènìyàn Fir‘aon wò ṣíwájú wọn. Òjíṣẹ́ alápọ̀n-ọ́nlé sì dé wá bá wọn.

:18

(Ó sọ pé): “Ẹ kó àwọn ẹrúsìn Allāhu lé mi lọ́wọ́. Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín.

:19

Ẹ má ṣe ṣègbéraga sí Allāhu. Dájúdájú èmi ti mú ẹ̀rí pọ́nńbélé wá ba yín.

:20

Dájúdájú Èmi sá di Olúwa mi àti Olúwa yín pé kí ẹ má ṣe sọ mí ní òkò.

:21

Tí ẹ kò bá sì gbà mí gbọ́, ẹ fi mí sílẹ̀ jẹ́.”

:22

Nítorí náà, ó pe Olúwa rẹ̀ pé dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni ìjọ ẹlẹ́sẹ̀.

:23

(Allāhu sọ pé): “Mú àwọn ẹrúsìn Mi rìn ní alẹ́ (nítorí pé) wọn yóò tọ̀ yín lẹ́yìn.

:24

Kí o sì fi agbami odò sílẹ̀ ní yíyanu sílẹ̀. Dájúdájú àwọn ni ọmọ ogun tí A máa tẹ̀rì sínú agbami.

:25

Mélòó mélòó nínú àwọn ọgbà oko àti odò ìṣẹ́lẹ̀rú tí wọ́n fi sílẹ̀ (lẹ́yìn ìparun wọn).

:26

Àti àwọn irúgbìn pẹ̀lú àyè àpọ́nlé (tí wọ́n fi sílẹ̀).

:27

Àti ìdẹ̀ra tí wọ́n ń gbádùn nínú rẹ̀ (ṣíwájú ìparun wọn).

:28

Báyẹn (ni ọ̀rọ̀ wọn ṣe rí). A sì jogún (ìlú) wọ́n fún ìjọ ènìyàn mìíràn.

:29

Nígbà náà, sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò sunkún wọn. Wọn kò sì fi ìyà wọn falẹ̀.

:30

Dájúdájú A gba àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl là nínú ìyà yẹpẹrẹ.

:31

(A là wọ́n) lọ́wọ́ Fir‘aon. Dájúdájú ó jẹ́ onígbèéraga. Ó sì wà nínú àwọn alákọyọ.

:32

A kúkú ṣà wọ́n lẹ́ṣà lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò tiwọn) pẹ̀lú ìmọ̀ (tí a mọ̀ nípa wọn).1

:33

A sì fún wọn ní àwọn àmì tí àdánwò pọ́nńbélé wà nínú rẹ̀.

:34

Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ń wí pé:

:35

“Kò sí ikú kan àyàfi ikú àkọ́kọ́ (tí ó pa wá nílé ayé). Wọn kò sì níí gbé wa dìde.

:36

(Bí bẹ́ẹ̀ kọ́), ẹ mú àwọn bàbá wa wá tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”

:37

Ṣé àwọn ni wọ́n lóore jùlọ ni tàbí àwọn ènìyàn Tubba‘u àti àwọn tó ṣíwájú wọn? A pa wọ́n rẹ́; dájúdájú wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀.

:38

A kò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin méjèèjì pẹ̀lú eré ṣíṣe.

:39

A kò dá àwọn méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.

:40

Dájúdájú ọjọ́ òpínyà (ìyẹn, ọjọ́ àjíǹde) ni àkókò àdéhùn fún gbogbo wọn pátápátá.

:41

Ní ọjọ́ tí ọ̀rẹ́ kan kò níí fi kiní kan rọ ọ̀rẹ́ kan lọ́rọ̀. A kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.

:42

Àyàfi ẹni tí Allāhu bá kẹ́. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

:43

Dájúdájú igi zaƙūm

:44

ni oúnjẹ ẹlẹ́ṣẹ̀.

:45

Ó dà bí ògéré epo gbígbóná tí ń hó nínú ikùn

:46

(tó) dà bí híhó omi tó gbóná gan-an.

:47

Ẹ mú un. Kí ẹ wọ́ ọ sáàrin gbùngbùn inú iná Jẹhīm.

:48

Lẹ́yìn náà, ẹ rọ́ ìyà olómi gbígbóná lé e lórí.

:49

Tọ́ ọ wò (ṣebí) dájúdájú ìwọ ni alágbára, alápọ̀n-ọ́nlé (gẹ́gẹ́ bí ó ṣe pe ara rẹ).

:50

Dájúdájú (ìyà) èyí ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣeyèméjì nípa rẹ̀!

:51

Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù Allāhu yóò wà ní àyè ìfàyàbalẹ̀.

:52

(Wọn yóò wà) nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra pẹ̀lú àwọn omi ìṣẹ́lẹ̀rú (ní ìsàlẹ̀ rẹ̀).

:53

Wọn yóò máa wọ aṣọ àrán fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ àti àrán tó nípọn; wọn yó sì máà kọjú síra wọn (sọ̀rọ̀).

:54

Báyẹn (ni ọ̀rọ̀ wọn yó ṣe rí). A sì máa fi àwọn obìnrin ẹlẹ́yinjú-ẹgẹ́ ṣe ìyàwó fún wọn.

:55

Wọn yóò máa bèèrè fún gbogbo n̄ǹkan eléso nínú (Ọgbà Ìdẹ̀ra) lẹ́ni ìfàyàbalẹ̀.

:56

Wọn kò níí tọ́ ikú wò níbẹ̀ àyàfi ikú àkọ́kọ́ (tí wọ́n ti kú nílé ayé). (Allāhu) sì máa ṣọ́ wọn níbi ìyà iná Jẹhīm.

:57

Ó jẹ́ oore àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Ìyẹn ni èrèǹjẹ ńlá.

:58

Nítorí náà, A ṣe (al-Ƙur’ān) ní ìrọ̀rùn lórí ahọ́n rẹ̀ nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.

:59

Nítorí náà, máa retí Dájúdájú àwọn náà ń retí.