Gbogbo Islam Library

19 - Mary - Maryam

:1

Kāf hā yā ‘aēn sọ̄d. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)1

:2

(Èyí ni) ìrántí nípa ìkẹ́ tí Olúwa Rẹ ṣe fún ẹrúsìn Rẹ̀ (Ànábì) Zakariyyā.

:3

(Rántí) nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ ní ìpè ìkọ̀kọ̀.

:4

Ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú eegun ara mi ti lẹ, orí (mi) ti kún fún ewú, èmi kò sì níí pasán nípa bí mo ṣe ń pè Ọ́, Olúwa mi.

:5

Àti pé dájúdájú mò ń páyà àwọn ìbátan mi lẹ́yìn (ikú) mi. Ìyàwó mi sì jẹ́ àgàn. Nítorí náà, ta mí lọ́rẹ láti ọ̀dọ̀ Rẹ ọmọ rere kan,

:6

(tí) ó máa jogún mi, tí ó sì máa jogún àwọn ẹbí (Ànábì) Ya‘ƙūb. Kí O sì ṣe é ní ẹni tí O yọ́nú sí, Olúwa mi.”

:7

Zakariyyā, dájúdájú Àwa máa fún ọ ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin kan, orúkọ rẹ̀ ni Yahyā. A kò fún ẹnì kan ní (irú) orúkọ (yìí) rí ṣíwájú (rẹ̀).

:8

Ó sọ pé: “Olúwa mi, báwo ni mo ṣe máa ní ọmọ nígbà tí ìyàwó mi jẹ́ àgàn, tí mo sì ti di àgbàlagbà gan-an.”

:9

(Mọlāika) sọ pé: “Báyẹn ni (ó máa rí).” Olúwa rẹ sọ pé: “Ó rọrùn fún Mi. Mó kúkú dá ìwọ náà ṣíwájú (rẹ̀), nígbà tí ìwọ kò tí ì jẹ́ n̄ǹkan kan.”

:10

(Zakariyyā) sọ pé: “Olúwa mi, fún mi ní àmì kan.” (Mọlāika) sọ pé: “Àmì rẹ ni pé, o ò níí lè bá ènìyàn sọ̀rọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta, kì í ṣe ti àmódi.”

:11

Nígbà náà, ó jáde sí àwọn ènìyàn rẹ̀ láti inú ilé ìjọ́sìn. Ó sì tọ́ka sí wọn pé kí wọ́n máa ṣe àfọ̀mọ́ (fún Allāhu) ní òwúrọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́.

:12

Yahyā, mú Tírà náà dání dáradára. A sì fún un ní àgbọ́yé ẹ̀sìn láti kékeré.

:13

(Ànábì Yahyā jẹ́) ìkẹ́ àti ẹni mímọ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa. Ó sì jẹ́ olùbẹ̀rù (Allāhu).

:14

(Ó tún jẹ́) oníwà rere sí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì. Kò sì jẹ́ ajẹninípá, olùyapa.

:15

Àlàáfíà ni fún un ní ọjọ́ tí wọ́n bí i, àti ní ọjọ́ tí ó máa kú àti ní ọjọ́ tí A óò gbé e dìde láàyè (ní Ọjọ́ Àjíǹde).

:16

Sọ ìtàn Mọryam tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. (Rántí) nígbà tí ó yẹra kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ sí àyè kan ní ìlà òòrùn.

:17

Ó mú gàgá kan (láti fi ara rẹ̀ pamọ́) fún wọn. A sì rán mọlāika Wa sí i. Ó sì fara hàn án ní àwòrán abara pípé.1

:18

(Mọryam) sọ pé: “Èmi sá di Àjọkẹ́-ayé kúrò lọ́dọ̀ rẹ, tí o bá jẹ́ olùbẹ̀rù (Allāhu).”1

:19

(Mọlāika) sọ pé: “Èmi ni Òjíṣẹ́ Olúwa rẹ, (Ó rán mi sí ọ) pé kí n̄g fún ọ ní ọmọkùnrin mímọ́ kan.”1

:20

Ó sọ pé: “Báwo ni mo ṣe máa ní ọmọ nígbà tí abara kan kò fọwọ́ kàn mí, tí èmi kò sì jẹ́ alágbèrè.”

:21

(Mọlāika) sọ pé: “Báyẹn ló máa rí.” Olúwa rẹ sọ pé: “Ó rọrùn fún mi. Àti pé nítorí kí Á lè ṣe é ní àmì fún àwọn ènìyàn ni. Ó sì jẹ́ ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa. Ó tún jẹ́ ọ̀rọ̀ tí A ti parí (tí ó gbọ́dọ̀ wá sí ìmúṣẹ.)”

:22

Nítorí náà, ó lóyún rẹ̀. Ó sì yẹra pẹ̀lú rẹ̀ sí àyè kan tó jìnnà.

:23

Ìrọbí ọmọ sì mú un wá sí ìdí igi dàbínù. Ó sọ pé: “Háà! Kí n̄g ti kú ṣíwájú èyí, kí n̄g sì ti di ẹni tí wọ́n ti gbàgbé pátápátá.”

:24

Nígbà náà, (mọlāika) pè é láti ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: "Má ṣe banújẹ́. Dájúdájú Olúwa rẹ ti ṣe odò kékeré kan sí ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ rẹ.

:25

Mi igi dàbínù náà sọ́dọ̀ rẹ, kí dàbínú tútù, tó tó ká jẹ sì máa jábọ́ sílẹ̀ fún ọ.

:26

Nítorí náà, jẹ, mu kí ojú rẹ sì tutù. Tí o bá sì rí ẹnì kan nínú abara, sọ fún un pé: “Dájúdájú mo jẹ́jẹ̀ẹ́ ìkẹ́nuró fún Àjọkẹ́-ayé. Nítorí náà, èmi kò níí bá ènìyàn kan sọ̀rọ̀ ní òní.”

:27

Ó sì mú ọmọ náà wá bá àwọn ènìyàn rẹ̀ (ní ẹni tí) ó gbé e dání. Wọ́n sọ pé: “Mọryam, dájúdájú o ti gbé n̄ǹkan aburú ńlá wá.

:28

Arábìnrin Hārūn, bàbá rẹ kì í ṣe ènìyàn burúkú. Àti pé ìyá rẹ kì í ṣe alágbèrè.”

:29

Ó sì tọ́ka sí ọmọ náà. Wọ́n sọ pé: “Báwo ni a ó ṣe bá ẹni tó wà lórí ìtẹ́, tó jẹ́ ọmọ òpóǹló sọ̀rọ̀?”

:30

(Ọmọ náà) sọ̀rọ̀ pé: “Dájúdájú ẹrú Allāhu ni èmi. (Allāhu) fún mi ní Tírà. Ó sì ṣe mí ní Ànábì. 1

:31

Ó ṣe mí ní ẹni ìbùkún ní ibikíbi tí mo bá wà. Ó pa mí láṣẹ ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ lódiwọ̀n ìgbà tí mo bá wà nípò alààyè (lórí ilẹ̀ ayé).

:32

(Ó ṣe mí ní) oníwà rere sí ìyá mi. Kò sì ṣe mí ní ajẹninípá, olórí burúkú.

:33

Àlàáfíà ni fún mi ní ọjọ́ tí wọ́n bí mi, àti ní ọjọ́ tí mo máa kú àti ní ọjọ́ tí Wọ́n á gbé mi dìde ní alààyè (ní Ọjọ́ Àjíǹde).”

:34

Ìyẹn ni (Ànábì) ‘Īsā ọmọ Mọryam. (Èyí jẹ́) ọ̀rọ̀ òdodo tí àwọn (yẹhudi àti nasọ̄rọ̄) ń ṣeyèméjì nípa rẹ̀.

:35

Kò yẹ fún Allāhu láti sọ ẹnì kan kan di ọmọ. Mímọ́ ni fún Un. Nígbà tí Ó bá pèbùbù kiní kan, Ó kàn máa sọ fún un pé: “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.

:36

Àti pé dájúdájú Allāhu ni Olúwa mi àti Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Èyí ni ọ̀nà tààrà.

:37

Àwọn ìjọ (yẹhudi àti nasọ̄rọ̄) sì yapa-ẹnu (lórí èyí) láààrin ara wọn. Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ (ní àsìkò) ìjẹ́rìí gban̄gba l’ọ́jọ́ ńlá (Ọjọ́ Àjíǹde).

:38

Kí ni wọn kò níí gbọ́, kí sì ni wọn kò níí rí ní ọjọ́ tí wọn yóò wá bá Wa!Ṣùgbọ́n àwọn alábòsí ní ọjọ́ náà ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.

:39

Ṣèkìlọ̀ ọjọ́ àbámọ̀ fún wọn nígbà tí A bá parí ọ̀rọ̀, (pé kò níí sí ikú mọ́, àmọ́) wọ́n wà nínú ìgbàgbéra báyìí ná, wọn kò sì gbàgbọ́.

:40

Dájúdájú Àwa l’A máa jogún ilẹ̀ àti àwọn tó ń bẹ lórí rẹ̀. Ọ̀dọ̀ Wa sì ni wọn yóò da yín padà sí.

:41

Mú (ìtàn) ’Ibrọ̄hīm wá sí ìrántí (bí ó ṣe) wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ olódodo pọ́nńbélé, (ó sì jẹ́) Ànábì.

:42

Rántí nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Bàbá mi, nítorí kí ni o fi ń jọ́sìn fún ohun tí kò gbọ́rọ̀, tí kò ríran, tí kò sì lè rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ kan kan.

:43

Bàbá mi, dájúdájú ìmọ̀ tí ìwọ kò ní ti dé bá mi. Nítorí náà, tẹ̀lé mi, kí n̄g fi ọ̀nà tààrà mọ̀ ọ́.

:44

Bàbá mi, má ṣe bọ Èṣù. Dájúdájú Èṣù jẹ́ olùyapa àṣẹ Àjọkẹ́-ayé.

:45

Bàbá mi, dájúdájú èmi ń páyà pé kí ìyà kan láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé má fọwọ́ bà ọ́ nítorí kí ìwọ má baà di ọ̀rẹ́ Èṣù (nínú Iná).”

:46

(Bàbá rẹ̀) wí pé: “Ṣé ìwọ yóò kọ àwọn ọlọ́hun mi sílẹ̀ ni, ’Ibrọ̄hīm? Dájúdájú tí o ò bá jáwọ́ (nínú ohun tí ò ń sọ), dájúdájú mo máa lẹ̀ ọ́ lókò pa. Tíẹ̀ yẹra fún mi wọ́ọ́rọ́wọ́ ná.”

:47

(’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “Àlàáfíà kí ó máa bá ọ. Mo máa bá ọ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa mi. Dájúdájú Ó jẹ́ Olóore mi.

:48

Àti pé mo máa yẹra fún ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. Èmi yó sì máa pe Olúwa mi. Ó sì súnmọ́ pé èmi kò níí pasán pẹ̀lú àdúà mi sí Olúwa mi.”

:49

Nígbà tí ó yẹra fún àwọn àti n̄ǹkan tí wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, A sì ta á lọ́rẹ (ọmọ), ’Ishāƙ àti Ya‘ƙūb (ọmọọmọ rẹ̀). A sì ṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní Ànábì.1

:50

Àti pé A ta wọ́n lọ́rẹ láti inú ìkẹ́ Wa. A sì fi òdodo sórí ahọ́n gbogbo àwọn ènìyàn nìpa wọn (ìyẹn ni pé, gbogbo ìjọ ẹlẹ́sìn ló ń sọ̀rọ̀ wọn ní dáadáa).

:51

Sọ ìtàn (Ànábì) Mūsā tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ ẹni-ẹ̀ṣà, ó jẹ́ Òjíṣẹ́, (ó tún jẹ́) Ànábì.

:52

A pè é ní ẹ̀bá àpáta ní apá ọwọ́ ọ̀tún (Mūsā). A sì mú un súnmọ́ tòsí láti bá a sọ̀rọ̀.

:53

A sì fi arákùnrin rẹ̀, Hārūn, (tí ó jẹ́) Ànábì, ta á lọ́rẹ láti inú ìkẹ́ Wa.

:54

Sọ ìtàn (Ànábì) ’Ismọ̄‘īl tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ olùmú-àdéhùn-ṣẹ, ó jẹ́ Òjíṣẹ́, (ó tún jẹ́) Ànábì.

:55

Ó máa ń pa ará ilé rẹ̀ ní àṣẹ ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ. Ó sì jẹ́ ẹni ìyọ́nú lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀.

:56

Sọ ìtàn (Ànábì) ’Idrīs tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ olódodo pọ́nńbélé, (ó sì jẹ́) Ànábì.

:57

A sì gbé e sí àyè gíga (nínú sánmọ̀).

:58

Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ṣe ìdẹ̀ra fún nínú àwọn Ànábì, nínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ (Ànábì) Ādam àti nínú àwọn tí A gbé gun ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú (Ànábì) Nūh àti nínú àrọ́mọdọ́mọ (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti ’Isrọ̄’īl àti nínú àwọn tí A ti fi mọ̀nà, tí A sì ṣà lẹ́ṣà. Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Àjọkẹ́-ayé fún wọn, wọ́n máa dojú bolẹ̀; tí wọ́n á foríkanlẹ̀, tí wọ́n á sì máa sunkún.

:59

Àwọn àrólé kan sì rólé lẹ́yìn wọn, tí wọ́n rá ìrun kíkí láre, tí wọ́n tẹ̀lé àwọn adùn. Láìpẹ́ wọn máa pàdé òfò (nínú Iná).

:60

Àyàfi ẹni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn ni wọn yóò wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. A ò sì níí ṣàbòsí kan kan sí wọn.

:61

(Wọn yóò wọ inú) àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére tí Àjọkẹ́-ayé ṣe ní àdéhùn ní ìkọ̀kọ̀fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Dájúdájú (Allāhu), àdéhùn Rẹ̀ ń bọ̀ wá ṣẹ.

:62

Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ nínú rẹ̀ àfi àlàáfíà. Ìjẹ-ìmu wọn wà nínú rẹ̀ ní òwúrọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́.

:63

Ìyẹn ni Ọgbà Ìdẹ̀ra tí A óò jogún rẹ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ olùbẹ̀rù (Mi) nínú àwọn ẹrúsìn Wa.

:64

Àwa (mọlāika) kì í sọ̀kalẹ̀ àyàfi pẹ̀lú àṣẹ Olúwa rẹ. TiRẹ̀ ni ohun tí ń bẹ níwájú wa, ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn wa àti ohun tí ń bẹ láààrin (méjèèjì) yẹn. Àti pé Olúwa rẹ kì í ṣe onígbàgbé.

:65

Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Nítorí náà, jọ́sìn fún Un, kí ó sì ṣe sùúrù lórí ìjọ́sìn Rẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí ó tún ń jẹ́ orúkọ Rẹ̀?

:66

Ènìyàn ń wí pé: “Ṣé nígbà tí mo bá kú, wọn yóò tún mú mi jáde láìpẹ́ ní alààyè?”

:67

Ṣé ènìyàn kò rántí pé dájúdájú Àwa ni A ṣẹ̀dá rẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ nígbà tí kò tí ì jẹ́ n̄ǹkan kan?

:68

Nítorí náà, mo fi Olúwa rẹ búra; dájúdájú A máa kó àwọn àti àwọn èṣù jọ. Lẹ́yìn náà, dájúdájú A máa mú wọn wá sí ayíká iná Jahanamọ lórí ìkúnlẹ̀.

:69

Lẹ́yìn náà, dájúdájú A máa mú jáde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan ẹni tí ó le jùlọ nínú wọn níbi ẹ̀ṣẹ̀ dídá sí Àjọkẹ́-ayé.

:70

Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa nímọ̀ jùlọ nípa àwọn tó lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ sí wíwọ inú Iná.

:71

Kò sí ẹnì kan nínú yín àfi kí ó débẹ̀ (àfi kí ó gba ibẹ̀ kọjá). Ó di dandan kí ó ṣẹlẹ̀ lọ́dọ̀ Olúwa rẹ.

:72

Lẹ́yìn náà, A máa gba àwọn tó bẹ̀rù (Allāhu) là. A sì máa fi àwọn alábósì sílẹ̀ sínú Iná lórí ìkúnlẹ̀.1

:73

Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa tó yanjú fún wọn, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yóò sọ fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo pé: “Èwo nínú ìjọ méjèèjì (àwa tàbí ẹ̀yin) ló lóore jùlọ ní ibùgbé, ló sì dára jùlọ ní ìjókòó (afẹ́)?”

:74

Àti pé mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn, tí wọ́n dára jùlọ ní ọrọ̀ (ayé) àti ní ìrísí!

:75

Sọ pé: “Ẹni tí ó bá wà nínú ìṣìnà, Àjọkẹ́-ayé yó sì fẹ (ìṣìnà) lójú fún un tààrà, títí di ìgbà tí wọn máa rí ohun tí wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún wọn, yálà ìyà tàbí Àkókò náà. Nígbà náà, wọn yóò mọ ẹni tí ó burú jùlọ ní ipò, tí ó sì lẹ jùlọ ní ọmọ ogun.

:76

Allāhu yó sì ṣàlékún ìmọ̀nà fún àwọn tó mọ̀nà. Àwọn iṣẹ́ rere ẹlẹ́san gbére lóore jùlọ ní ẹ̀san, ó sì lóore jùlọ ní ibùdésí lọ́dọ̀ Olúwa rẹ.

:77

Sọ fún mi nípa ẹni tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, tí ó sì wí pé: “Dájúdájú wọn yóò fún mi ní dúkìá àti ọmọ!”

:78

Ṣé ó rí ìkọ̀kọ̀ ni tàbí ó rí àdéhùn kan gbà lọ́dọ̀ Àjọkẹ́-ayé?

:79

Rárá. A máa ṣàkọsílẹ̀ ohun tó ń wí. A sì máa fẹ ìyà lójú fún un tààrà.

:80

A ó sì jogún ohun tó ń wí fún un. Ó sì máa wá bá Wa ní òun nìkan.

:81

Wọ́n sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu nítorí kí wọ́n lè fún wọn ní agbára.

:82

Rárá. Wọ́n máa tako ìjọ́sìn wọn, wọ́n si máa di ọ̀tá wọn.

:83

Ṣé ìwọ kò wòye pé dájúdájú Àwa ń dẹ àwọn èṣù sí àwọn aláìgbàgbọ́ ni, tí wọ́n sì ń gùn wọ́n gan-an (síbi ẹ̀ṣẹ̀)?

:84

Nítorí náà, má ṣe kánjú nípa (ìyà) wọn. A kúkú ń ka (ọjọ́) fún wọn ní kíkà tààrà.

:85

(Rántí) ọjọ́ tí A óò kó àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) jọ sọ́dọ̀ Àjọkẹ́-ayé lórí n̄ǹkan ìgùn.

:86

A sì máa da àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ sínú iná Jahanamọ wìtìwìtì.

:87

Wọn kò níí ní ìkápá ìṣìpẹ̀ àfi ẹni tí ó bá gba àdéhùn láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé.

:88

Wọ́n wí pé: “Àjọkẹ́-ayé fi ẹnì kan ṣe ọmọ.”

:89

Dájúdájú ẹ ti mú n̄ǹkan aburú wá.

:90

Àwọn sánmọ̀ fẹ́rẹ̀ fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nítorí rẹ̀, ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, àwọn àpáta sì fẹ́rẹ̀ dàwó lulẹ̀ gbì

:91

fún wí pé wọ́n pe ẹnì kan ní ọmọ Àjọkẹ́-ayé.

:92

Kò sì yẹ fún Àjọkẹ́-ayé láti fi ẹnì kan ṣe ọmọ.

:93

Kò sí ẹnì kan nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àyàfi kí ó wá bá Àjọkẹ́-ayé ní ipò ẹrúsìn.

:94

Dájúdájú (Allāhu) mọ̀ wọ́n. Ó sì ka òǹkà wọn tààrà.

:95

Gbogbo wọn yó sì wá bá A ní Ọjọ́ Àjíǹde ní ìkọ̀ọ̀kan.

:96

Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, Àjọkẹ́-ayé yóò fi ìfẹ́ sáààrin wọn.

:97

Nítorí náà, A kúkú ṣe kíké al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn (fún ọ) pẹ̀lú èdè abínibí rẹ nítorí kí o lè fi ṣe ìró ìdùnnú fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) àti nítorí kí o lè fi ṣe ìkìlọ̀ fún ìjọ oníyàn-jíjà.

:98

Mélòó mélòó nínú ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn! Ǹjẹ́ o gbọ́ ìró ẹnì kan kan nínú wọn mọ́ tàbí (ǹjẹ́) o gbọ́ ohùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ wọn bí?