Gbogbo Islam Library

15 - The Rocky Tract - Al-Ĥijr

:1

’Alif lām rọ̄. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà náà àti (àwọn āyah) al-Ƙur’ān tó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.

:2

Ó ṣeé ṣe kí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nífẹ̀ẹ́ sí pé àwọn ìbá sì ti jẹ́ mùsùlùmí (nílé ayé).

:3

Fi wọ́n sílẹ̀, kí wọ́n jẹ, kí wọ́n gbádùn, kí ìrètí (ẹ̀mí gígùn) kó àìrójú ráàyè bá wọn (láti ṣẹ̀sìn); láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.

:4

A kò pa ìlú kan run rí àfi kí ó ní àkọsílẹ̀ tí A ti mọ̀.

:5

Kò sí ìjọ kan (tí ó parun) ṣíwájú àkókò rẹ̀ (nínú Laohul-Mahfuuṭḥ); wọn kò sì níí sún un ṣíwájú fún wọn.

:6

Wọ́n wí pé: “Ìwọ tí wọ́n sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún, dájúdájú wèrè ni ọ́.

:7

Kí ni kò jẹ́ kí ìwọ mú àwọn mọlāika wá bá wa, tí ìwọ bá wà nínú àwọn olódodo?”

:8

A kò níí sọ mọlāika kalẹ̀ bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo. Wọn kò sì níí lọ́ wọn lára mọ́ nígbà náà (tí àwọn mọlāika bá sọ̀kalẹ̀).

:9

Dájúdájú Àwa l’A sọ Tírà Ìrántí kalẹ̀ (ìyẹn al-Ƙur’ān). Dájúdájú Àwa sì ni Olùṣọ́ rẹ̀.

:10

Dájúdájú ṣíwájú rẹ A ti rán (àwọn Òjíṣẹ́) níṣẹ́ sí àwọn ìjọ, àwọn ẹni àkọ́kọ́.

:11

Òjíṣẹ́ kan kò sì níí dé bá wọn àfi kí wọ́n máa fi ṣe yẹ̀yẹ́.

:12

Báyẹn náà ni A ṣe máa fi (àìsàn pípe al-Ƙur'ān nírọ́) sínú ọkàn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ (nínú ìjọ tìrẹ náà).

:13

Wọn kò níí gbà á gbọ́; ìṣe (Allāhulórí) àwọn ẹni àkọ́kọ́ kúkú ti ré kọjá.

:14

Tí ó bá jẹ́ pé A ṣí ìlẹ̀kùn kan sílẹ̀ fún wọn láti inú sánmọ̀, tí wọn kò sì yé gbabẹ̀ gùnkè lọ (sínú sánmọ̀),

:15

dájúdájú wọ́n á wí pé: “Wọ́n kan fi n̄ǹkan bo ojú wa ni. Rárá, ènìyàn tí wọ́n ń dan ni àwa sẹ́.”

:16

A kúkú fi àwọn ibùsọ̀ ìràwọ̀ sínú sánmọ̀ (ayé). A ṣe é ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn olùwòran.

:17

A sì ṣọ́ ọ kúrò lọ́dọ̀ gbogbo èṣù, ẹni ẹ̀kọ̀.1

:18

Àfi (èṣù) tí ó bá jí ọ̀rọ̀ gbọ́. Nígbà náà sì ni ògúnná pọ́nńbélé yó tẹ̀lé e láti ẹ̀yìn.

:19

Ilẹ̀, A tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ. A sì ju àwọn àpáta tó dúró gbagidi sínú rẹ̀. A sì mú gbogbo n̄ǹkan tí ó ní òdíwọ̀n hù jáde láti inú rẹ̀.

:20

A ṣe ọ̀nà ìjẹ-ìmu sínú (ilé ayé) fun ẹ̀yin àti àwọn tí ẹ̀yin kò lè pèsè fún.

:21

Kò sì sí kiní kan àfi kí ilé-ọrọ̀ rẹ̀ wà lọ́dọ̀ Wa. Àwa kò sì níí sọ̀ ọ́ kalẹ̀ àfi pẹ̀lú òdíwọ̀n tí A ti mọ̀.

:22

Àti pé A rán àwọn atẹ́gùn láti kó àwọn ẹ̀ṣújò jọ. A sì sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Nítorí náà, A fún yín mu. Ẹ̀yin sì kọ́ ni ẹ kó omi òjò jọ (sójú sánmọ̀).

:23

Dájúdájú Àwa, Àwa ń sọ (ẹ̀dá) di alààyè. A sì ń sọ ọ́ di òkú. Àwa sì ni A óò jogún (ẹ̀dá).

:24

Àti pé dájúdájú A mọ àwọn olùgbawájú nínú yín. Dájúdájú A sì mọ àwọn olùgbẹ̀yìn.

:25

Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun l’Ó máa kó wọn jọ. Dájúdájú Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.

:26

Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara amọ̀ tó ń dún koko, tó ti pàwọ̀dà.

:27

Àti pé àlùjànnú, A ṣẹ̀dá rẹ̀ ṣíwájú (ènìyàn) láti ara iná alátẹ́gùn gbígbóná tí kò ní èéfín.

:28

(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ fún àwọn mọlāika pé: “Dájúdájú Èmi yóò ṣe ẹ̀dá abara kan láti ara amọ̀ tó ń dún koko, tó ti pàwọ̀dà.

:29

Nígbà tí Mo bá ṣe é tó gún régétán, tí Mo fẹ́ ẹ̀mí sí i (lára) nínú ẹ̀mí Mi (tí Mo dá), nígbà náà ẹ dojú bolẹ̀ fún un ní olùforíkanlẹ̀-kíni.”1

:30

Nítorí náà, àwọn mọlāika, gbogbo wọn pátápátá sì forí kanlẹ̀ kí i.

:31

Àyàfi ’Iblīs. Ó kọ̀ láti wà nínú àwọn olùforíkanlẹ̀-kíni náà.

:32

(Allāhu) sọ pé: “’Iblīs, kí ló dí ọ lọ́wọ́ láti wà nínú àwọn olùforíkanlẹ̀-kíni?”

:33

Ó wí pé: “Èmi kò níí forí kanlẹ̀ kí abara kan tí O ṣẹ̀dá rẹ̀ láti ara amọ̀ tó ń dún koko, tó ti pàwọ̀dà.”

:34

(Allāhu) sọ pé: “Nítorí náà, jáde kúrò nínú rẹ̀. Dájúdájú, ìwọ ni ẹni-ẹ̀kọ̀.

:35

Àti pé, dájúdájú ègún ń bẹ lórí rẹ títí di Ọjọ́ ẹ̀san.”

:36

Ó wí pé: “Olúwa mi, lọ́ mi lára títí di Ọjọ́ tí wọ́n máa gbé ẹ̀dá dìde.”

:37

(Allāhu) sọ pé: “Dájúdájú ìwọ wà lára àwọn tí A óò lọ́ lára

:38

títí di ọjọ́ àkókò tí A ti mọ.”1

:39

Ó wí pé: “Olúwa mi, fún wí pé O ti ṣe mí ní ẹni anù, dájúdájú emí yóò ṣe (aburú) ní ọ̀ṣọ́ fún wọn lórí ilẹ̀. Dájúdájú èmi yó sì kó gbogbo wọn sínú anù

:40

àfi àwọn ẹrúsìn Rẹ, àwọn tí O ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).”1

:41

(Allāhu) sọ pé: “(Ìdúróṣinṣin lójú) ọ̀nà tààrà, Ọwọ́ Mi ni èyí wà.”

:42

Dájúdájú àwọn ẹrúsìn Mi, kò sí agbára kan fún ọ lórí wọn, àyàfi ẹni tí ó bá tẹ̀lé ọ nínú àwọn ẹni anù.

:43

Àti pé dájúdájú iná Jahanamọ ni àdéhùn fún gbogbo wọn.

:44

Àwọn ojú ọ̀nà méje ń bẹ fún (iná). Àtúnpín tún wà fún ojú-ọ̀nà kọ̀ọ̀kan.

:45

Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) máa wà nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra pẹ̀lú àwọn odò (tó ń ṣàn nísàlẹ̀ rẹ̀).

:46

(A máa sọ pé): “Ẹ wọ inú rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà ní olùfàyàbalẹ̀.”

:47

A sì máa yọ ohun tí ń bẹ nínú ọkàn wọn tó jẹ́ inúnibíni kúrò; (wọn yóò di) ọmọ-ìyá (ara wọn. Wọn yóò wà) lórí ibùsùn, tí wọn yóò kọjú síra wọn.

:48

Wàhálà kan kò níí bá wọn nínú rẹ̀. Wọn kò sì níí mú wọn jáde kúrò nínú rẹ̀.

:49

Fún àwọn ẹrúsìn Mi ní ìró pé dájúdájú Èmi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

:50

Àti pé dájúdájú ìyà Mi ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro.

:51

Fún wọn ní ìró nípa àlejò (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm.

:52

(Rántí) nígbà tí wọ́n wọlé tọ̀ ọ́, wọ́n sì sọ pé: “Àlàáfíà”. Ó sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀rù yín ń ba àwa.”

:53

Wọ́n sọ pé: “Má ṣe bẹ̀rù. Dájúdájú àwa yóò fún ọ ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin kan tí ó máa ní ìmọ̀.”

:54

Ó sọ pé: “Ṣé ẹ̀ ń fún mi ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí ọmọ) nígbà tí ogbó ti dé sí mi? Ìró ìdùnnú wo ni ẹ̀ ń fún mi ná?”

:55

Wọ́n sọ pé: “À ń fún ọ ní ìró ìdùnnú pẹ̀lú òdodo. Nítorí náà, má ṣe wà lára àwọn olùjákànmùná.”

:56

Ó sọ pé: “Kò mà sí ẹni tí ó máa jákànmùná nínú ìkẹ́ Olúwa Rẹ̀ bí kò ṣe àwọn olùṣìnà.”

:57

Ó sọ pé: “Kí tún ni ọ̀rọ̀ tí ẹ bá wá, ẹ̀yin Òjíṣẹ́?”

:58

Wọ́n sọ pé: “Dájúdájú Wọ́n rán wa níṣẹ́ sí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.

:59

Àfi ará ilé (Ànábì) Lūt. Dájúdájú àwa yóò gba wọn là pátápátá.

:60

Àfi ìyàwó rẹ̀; A ti kọ kádàrá rẹ̀ (pé) dájúdájú ó máa wà nínú àwọn tó máa ṣẹ́kù lẹ́yìn sínú ìparun.”

:61

Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ dé ọ̀dọ̀ ará ilé (Ànábì) Lūt,

:62

(Ànábì Lūt) sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀yin jẹ́ àjòjì ènìyàn.”

:63

Wọ́n sọ pé: “Rárá, a wá sọ́dọ̀ rẹ nítorí ohun tí wọ́n ń ṣeyèméjì nípa rẹ̀.

:64

A mú òdodo wá bá ọ ni. Àti pé dájúdájú olódodo ni àwa.

:65

Nítorí náà, mú ará ilé rẹ jáde ní apá kan òru. Kí o sì tẹ̀lé wọn lẹ́yìn. Ẹnì kan nínú yín kò sì gbọdọ̀ ṣíjú wo ẹ̀yìn wò. Kí ẹ sì lọ sí àyè tí wọ́n ń pa láṣẹ fún yín.”

:66

A sì jẹ́ kí ìdájọ́ ọ̀rọ̀ yìí hàn sí i pé dájúdájú A máa pa àwọn (ẹlẹ́ṣẹ̀) wọ̀nyí run pátápátá nígbà tí wọ́n bá mọ́júmọ́.

:67

Àwọn ará ìlú náà dé, wọ́n sì ń yọ̀ sẹ̀sẹ̀.

:68

(Ànábì Lūt) sọ pé: “Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni àlejò mi. Nítorí náà, ẹ má ṣe dójú tì mí.

:69

Kí ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì má ṣe yẹpẹrẹ mi.”

:70

Wọ́n wí pé: “Ǹjẹ́ àwa kò ti kọ̀ fún ọ (nípa gbígba àlejò) àwọn ẹ̀dá?”

:71

Ó sọ pé: “Àwọn ọmọbìnrin mi nìwọ̀nyí, tí ẹ bá ní n̄ǹkan tí ẹ fẹ́ (fi wọ́n) ṣe.”1

:72

(Allāhu sọ pé): “Mo fi ìṣẹ̀mí ìwọ (Ànábì Muhammad) búra;dájúdájú wọ́n kúkú wà nínú ìṣìnà àti àìmọ̀kan wọn, tí wọ́n ń pa rìdàrìdà.”

:73

Nítorí náà, ohùn igbe mú wọn nígbà tí òòrùn òwúrọ̀ yọ sí wọn.

:74

A sì sọ òkè ìlú wọn di ìsàlẹ̀ rẹ̀ (ìlú wọ́n dojú bolẹ̀). A tún rọ òjò òkúta amọ̀ (sísun) lé wọn lórí.

:75

Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn alárìíwòye.

:76

Dájúdájú (ìlú náà) kúkú wà lójú ọ̀nà (tí ẹ̀ ń tọ̀ lọ tọ̀ bọ̀).

:77

Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

:78

Àwọn ará ’Aekahnáà jẹ́ alábòsí.

:79

A sì gbẹ́san lára wọn. Dájújájú àwọn ìlú méjèèjì ló kúkú wà lójú ọ̀nà gban̄gba (tí ẹ̀ ń tọ̀ lọ tọ̀ bọ̀).

:80

Dájúdájú àwọn ará Ihò àpáta pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.

:81

A sì fún wọn ní àwọn àmì Wa. Àmọ́ wọ́n gbúnrí kúrò níbẹ̀.

:82

Wọ́n máa ń gbẹ́ àwọn ilé ìgbé ìfàyàbalẹ̀ sínú àwọn àpáta.

:83

Ohùn igbe sì mú wọn nígbà tí wọ́n mọ́júmọ́.

:84

Ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ kò sì rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ (níbi ìyà).

:85

A kò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan tó wà láààrin àwọn méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo. Dájúdájú Àkókò náà máa dé. Nítorí náà, ṣàmójúkúrò ní àmójúkúrò tó rẹwà.

:86

Dájúdájú Olúwa rẹ ni Ẹlẹ́dàá, Onímọ̀.

:87

Dájúdájú A fún ọ ní Sab‘u Mọthānī (ìyẹn, sūrah al-Fātihah) àti al-Ƙur’ān Ńlá.

:88

Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣíjú rẹ méjèèjì wo ohun tí A fi ṣe ìgbádún ayé fún oríṣiríṣi àwọn kan nínú àwọn aláìgbàgbọ́. Má ṣe banújẹ́ nítorí wọn. Kí o sì rẹ apá rẹ nílẹ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

:89

Kí o sì sọ pé: “Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé.”

:90

Gẹ́gẹ́ bí A ṣe sọ (ìyà) kalẹ̀ fún àwọn tó ń pín òdodo mọ́ irọ́;

:91

àwọn tí wọ́n sọ al-Ƙur’ān di ìpínkúpìn-ín,1

:92

Olúwa rẹ fi Ara Rẹ̀ búra fún ọ pé, A máa bi gbogbo wọn ní ìbéèrè

:93

nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

:94

Nítorí náà, kéde n̄ǹkan tí A pa láṣẹ fún ọ. Kí o sì ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọ̀ṣẹbọ.

:95

Dájúdájú Àwa yóò tó ọ (níbi aburú) àwọn oníyẹ̀yẹ́,

:96

àwọn tó ń mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.

:97

Àwa kúkú ti mọ̀ pé dájúdájú ohun tí wọ́n ń wí ń kó ìnira bá ọ.

:98

Nítorí náà, ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Olúwa rẹ.Kí o sì wà nínú àwọn olùforíkanlẹ̀ (fún Un).

:99

Jọ́sìn fún Olúwa rẹ títí àmọ̀dájú (ìyẹn, ikú) yóò fi dé bá ọ.